You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú agbébọn pa kọmíṣọ́nnà àti ọlọ́pàá, wọ́n dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá
Ọrọ eto abo to mẹhẹ ni orilẹede Naijiria ti wa di ojukeji bayii.
Awọn agbebọn lo maa tun ti ṣekupa kọmiṣọnna to n ri si owo awọn oṣiṣẹ fẹyinti nipinlẹ Kogi, Adebayo Solomon.
Lọjọ Abamẹta lawọn kọlọnbiti ẹda ọhun yinbọn fun Solomon ninu ọkọ rẹ nigba to n rinrin ajo lati ilu Ilorin si Kabba.
- Àlàyée Fídíò ẹsun tí wọ́n kan Baba Ijesha pé ó ṣe aṣamaṣe pẹ̀lú ọmọdé kan rèé
- Kò sí ẹ̀rí tó dájú tí a lè lò láti yọ Pantami kúró n'íjọba Buhari- Ilé aṣòfin l'Abuja
- Kò sí àwáwí fún ìwà Baba Ijesha àmọ... -Yomi Fabiyi
- Wo ìdí tí ìjọba Naijiria ṣe fòfin de gbogbo arìnrìnàjò láti India, Brazil àti Turkey
- Wọ́n ti wú òkú Iniobong tí wọ́n pa níbi tó ti ń wá iṣẹ́
- Gbankọgbì ọ̀rọ̀ tí Iyabo sọ sáwọn tó ń wú fídíò tí Baba Ijesha ti ṣépè fún un jáde rèé
- Àsìkò ti tó kí wọ́n yọ Buhari lórí oyè kí àlááfíà lè padà sí Naijiria - PFN, Kukah, Ighodalo
Wọn ti gbe oku kọmiṣọnna naa lọ si ile igbokusi ijọ ECWA to wa niluu Egbe.
Bakan naa ni a gbọ pe wọn tun ti ji alaga ijọba ilẹ ila oorun Yagba nipinlẹ naa, Pius Kolawole gbe lọ.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Kogi, Ayuba Ede ti sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
Wọn ko tii ri alaga kansu ila ooru Yagba ti wọn jigbe lọ di akoko ti a kọ iroyin yii.
Awọn agbebọn pa ọlọpaa lẹyin ikọlu si agọ ọlọpaa ni Ebonyi
Ẹwẹ, iroyin to tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Ebonyi sọ pe awọn janduku agbebọn kọlu agọ ọlọpaa Abaomege to wa ni ijọba ibilẹ Onicha nipinlẹ naa.
Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ, alẹ ọjọ Abamẹta lawọn kọlọnbiti ẹda naa ṣe ikọlu si agọ ọlọpaa ọhun nibi ti wọn dabọn bolẹ.
Koda, ọlọpaa kan ba iṣẹlẹ naa lọ ti omiran si farapa gẹgẹ bi ohun ti a gbọ.
Kọmiṣọnaa fun eto abo, Stanley Emegha lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ fun BBC.