Baba Ijesha: Iyabo Ojo, Esabod, Davido lápá kan, Yomi Fabiyi, Bukky Black lápá kejì lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha

Kii ṣe iroyin mọ pe gbajumọ oṣere Baba Ijesha n foju wina ofin lọwọ bayii lori ẹsun aṣemaṣe pẹlu ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla kan to jẹ ọmọ agbatọ fun gbajumọ alawada obinrin ni ti gbogbo aye mọ si Princess.

Lẹyin ti iroyin aṣemaṣe naa lu si agbami iroyin agbaye ni awọn eekan lawujọ gbogbo ti n sọrọ lori iṣẹlẹ naa. Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu iwa yii lawọn miran n pe fun suuru ti awọn kan si n gbẹri gbajumọ oṣere naa jẹ pe ko lee ṣe nnkan to jọ bẹẹ; kodan awọn miran tilẹ n pe okobo ni ko leeta putu rara.

Awọn to faake kọri pe gbajumọ oṣere naa gbọdọ fimu kata ofin

Iyabọ Ojo

Ni kete ti iroyin aṣemaṣe yii jade, lara awọn ti ko yee lọgun tantantan ni Iyabọ Ojo wa.

Koda o ti ṣee de ibi pe awọn eeyan kan lori ayelujara ti n pariwo pe aṣeju rẹ pọ abi boya o ni nnkan miran to wa bi dukuu laarin oun ati Baba Ijesha.

Amọṣa, Iyabọ Ojo ti ni ko si nnkan to wa laarin oun tabi ẹsan ti oun fẹ gba ju pe gẹgẹ bi obinrin, asiko to lati dide fun idaabobo awọn ọmọbinrin lawujọ nitori pe ọgbẹ ọkan ti ọpọ n gbe kiri lori awọn aṣemaṣe igba atijọ pọ pupọ lawujọ lode oni.

Esabod

Ninu ọrọ tirẹ, ilumọka asọrọgbayi lori ayelujara ni, Esther Aboderin ti ọpọ mọ si Esabod ni tirẹ ṣalaye pe ko ya oun lẹnu pupọ ju nitori Baba Ijesha ti fi irufẹ nnkan bẹẹ lọ oun pẹlu.

Ninu eto kan to ṣe loju opo Instagram rẹ, Esabod ni igbesẹ to ba tọ ni ki wọn gbe lori ọrọ naa.

Davido

Ọrọ yii tilẹ fa ibinu yọ fun Davido lori gbajumọ oṣere miran, Yomi Fabiyi.

Loju opo Instagram rẹ ni Davido fi fọto Fabiyi si to si kọ ọrọ kobakungbe kan sibẹ pẹlu.

Mercy Aigbe

Mercy Aigbe ni tirẹ ni inu to n bi oun kọja afẹnusọ.

"Ki Ọlọrun fiya jẹ gbogbo awọn to n gbe lẹyin Ijesha...Boya ẹ fẹ tabi ẹ kọ, idajọ ododo yoo waye! Ọlọrun maa dabo bo awọn ọmọ wa o ki o si maa ba wa tu aṣiri awọn ọdaran wọnyii".

Femi Adebayo

Gbajumọ oṣere naa ni oun duro lẹyin Princess ati ọmọdebinrin ọdun mẹrinla naa lai yẹsẹ.

Muyiwa Ademọla

Muyiwa Authentic ni idi ki idajọ ododo fẹsẹ mulẹ loun wa o gbogbo awọn to ba ṣebi si gbọdọ foju wina ofin.

Awọn to n gbe sẹyin Baba Ijesha

Yomi Fabiyi

Lara awọn ti ohun wọn ga ju lẹyin Baba Ijesha ni Yọmi Fabiyi wa.

Yọmi ni ko yẹ ki awọn eeyan ṣe idajọ gbajumọ oṣere naa lori ayelujara lai tii wo fidio bo ṣe ṣe ohun ti wọn pe o ṣe naa.

Eleyi fa ọpọlọpọ eebu ati ọrọ tako gbajumọ oṣere yii.

Foluke Daramola

Foluke Daramola ni ki wọn ye se idajọ Baba Ijesha bi wọn ti se fun Baba Suwe.

O ni ko yẹ ki ọkankan ninu awọn ọmọ oṣere tiata bẹrẹ si n ṣe idajọ Baba Ijesha nigba ti ile ẹjọ ko tii ṣedajọ tirẹ.

O fi kun un pe ọpọ ojuṣe lo wa lori awọn gbajumọ oṣere, nitori naa ki awọn akẹgbẹ oun ṣe mẹdọ lori iṣẹlẹ naa titi ti awọn agbofinro yoo fi pari iṣẹ wọn.

Foluke pari ọrọ rẹ pe, ọrọ ifipabanilopọ kii ṣe ohun ti eeyan le fi ọwọ yẹpẹrẹ mu, lai ro ti irufẹ ẹni ti wọn fi ẹsun naa kan.

Bukky Black

Lara awọn oṣere to gbe sẹyin Baba Ijesha ni Bukky Black wa.

Gbajumọ oṣere tiata naa to ni ẹyin ile oun ni baba Ijesha kọ ile si ṣalaye pe oun ko gbagbọ pe Baba Ijesha lee ṣe debi ti yoo maa ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọdebinrin kankan.