Alaafin Oyo àti Ooni Ile Ife bu ẹnu ẹàtẹ́ lu ìjọba àpapọ̀ lórí ètò àbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria

Alaafin ilu Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi ati Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ti fi aidunu wọn lede lori eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.

Awọn oriade mejeji lo sọ erongba wọn nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun kọkanlelaadọta Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Gani Adams.

Alaafin ni o ṣeni laanu pupọ pe awọn ajinigbe atawọn janduku n ṣọṣẹ lai si idiwọ kankan.

Kabiyesi wa ke si ijọba apapọ lati wa ojutu si ọrọ eto abo naa ki awọn olugbe guusu iwọ-oorun Naijiria le wa ni alaafia.

O ni awọn ajinigbe atawọn janduku n jaye fa mi lẹsẹ ki n tutọ ti ijọba ko si ri nnkan ṣe sii.

Ọba Aderemi tun ki Iba Gani Adams fun iṣẹ takuntakun to n ṣe ki ominira ilẹ Yoruba le ṣeeṣe, bẹẹ lo tun ni ki ijọba ji giri si eto abo.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, "Ọlọrun ati iṣẹ ọwọ rẹ lo yan Gani Adams si ipo to wa, o gba mi n nnkan bii ọdun marun ati ọpọ etutu pẹlu ifọwọsowọpọ awọn alalẹ ki wọn to yan si ipo to wa."

"Ko du ipo naa, ori lo gbe de ipo ọhun, adura mi si ni pe yoo ko awọn iran Yoruba jẹ pẹ."

Ẹwẹ, Ooni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ogunsi sọ pe awọn ori ade nilẹ Yoruba yoo maa ṣatilẹyin fun gbogbo akitiyan lati daabo bo awọn eeyan ilẹ naa.

Nigba to n sọrọ, Gani Adams rọ ijọba apapọ lati ri daju pe abo to dantọ wa fun awọn eeyan ilẹ Yoruba lapapọ.