Lizzy Anjorin: Ayọ̀ abara tín-tín! Lizzy Anjorin bímọ sí orílẹ́èdè Amẹrika

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ayọ abara tintin, gbajugbaja oṣere ati oniṣowo Lizzy Anjorin ti bi ọmọ tuntun lantilanti.

Lizzy fi fidio ti ounj ati ọkọ rẹ ti n dọwẹkẹ nigba to wa ninu oyun si oju opo Instagram rẹ.

''Oba aṣekan maku tun ti ṣe e, O maa n wo ọkan dajọ.

Ki i dajọ pẹlu ohun ti awọn eeyan ba n sọ nipa eeyan, oba pakanmire ti pa ẹgan mi rẹ patapata.

Lizzy ni ''ẹ darapọ mọ wa lati ṣajọyọ ore ti Ọlọrun ṣe fun wa.

Ọlọrun tun ti bu kun wa lẹẹkan sii, iyin ni gbogbo rẹ ja si, ALIHAMDULILLAH.

Ọjọ kinni oṣu karun un ọdun 2021 niluu Miami nipinlẹ Florida lorilẹede Amerika lo ti ṣẹlẹ.''

Lizzy ko sọ bo ya ọkunrin tabi obinrin ni ọmọ ti Eleduwa fi jinki oun ati ọkọ rẹ naa.

Bo tilẹ jẹ pe ọmọ akọkọ ti Lizzy yoo bi fun ọkọ rẹ to ṣeṣẹ fẹ niyii, o ti ni ọmọ kan to ti dagba tẹlẹ.