Coronavirus: Ẹ̀yin tí ẹ lọ ra aṣọ Okirika l'Ọjà Ọba Akure, ẹ lọ ṣàyẹ̀wò àrùn Coronavirus - Akeredolu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti rọ awọn eeyan to lọ ra aṣọ aloku ni Ọja Oba ilu Akure laipẹ yii lati lọ ṣe ayẹwo arun Coronavirus.

Akeredolu lo ṣo ọrọ naa nigba to n jabọ ibi iṣẹ de duro lori ọrọ Covi-19 ni ipinlẹ ọhun.

Ikede yii lo waye lẹyin ti obinrin kan to ni arun naa sa kuro nile itọju awọn alarun Coronavirus.

Lẹyin ọjọ diẹ ti awọn agbofinro ti n wa obinrin naa ni ọwọ tẹẹ ni Ọja Ọba nibi to ti n ta aṣọ 'Okirika' laarin ilu Akure.

Akeredolu tun sọ loju opo Twitter rẹ pe " A rọ awọn ara ilu to ti lọ ra aṣọ aloku ni Ọja Ọba, nibi ti a ti mu ẹni kẹtalelogoji to ni arun Covid-19 lati pese ara wọn fun ayẹwo ni kia kia."

Gomina ọhun ni igbesẹ yii ṣe pataki fun anfani ara wọn ati fun gbogbo ara ilu lapapọ.

Lẹyin naa lo kede pe apapọ awọnj to ti ni arun naa ti di mẹtalelogoji bayii.

Ọjà Ọba ní Akure ni ọwọ́ ọloọ́pàá ti tẹ aláàrùn Covid-19 tó sá kúrò ní ilé àyẹ̀wò - Akeredolu

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ alaarun Coronavirus to sa kuro nile iwosan to ti n gba iwosan ni Ọja Ọba ni Akure, ni ipinlẹ Ondo

Kọmisọnna fun eto ilẹra, Wahab Adegbenro sọ wi pe alaarun naa to jẹ obinrin ni ayẹwo fihna pe o ni arun Coronavirus ni ipinlẹ Imo amọ to salọ si ipinlẹ Ondo.

Adegbenro ni lẹyin ti obinrin naa salọ ni ijọba ipinlẹ Ondo ati Imo parapọ bẹrẹ si ni wa obinrin naa ki wọn to wa ri.

Wọn ni ibi ti obinrin naa ti n ta aṣọ aloku ni ọwọ ti tẹ ẹ.

Amọ, Kọmisọnna naa koju oro si iru iwa bayii ti o le fa ki aarun naa tankalẹ si.

Bẹẹ ni wọn wa rọ awọn eniyan lati tẹlẹ imọran ijọba lori ofin yiyagofunraẹni ti o le dẹkun itankalẹ arun Coronavirus.

Ti a ko ba gbagbe, Ajọ Amuṣẹya lori aarun Coronavirus ni ipinlẹ Imo lo ke gbajare pe eniyan mẹẹdọgbọn ti sa kuro ni ile ayẹwo aarun Coronavirus ni ipinlẹ Imo.