You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria rape cases: Ìyá àgbà ní ọkùnrin tó mutí yó náà fipá lòpọ̀ pẹ̀lú òun lójú oorun
Iya onile kan to n gbe ni Ijoko nipinlẹ Ogun ti salaye bi awakọ ọkọ akẹru kan to ti mu ọti yo, ṣe fipa ba a lopọ.
Nigba to n ba akọroyin sọrọ, iya arugbo naa, ti a fi orúkọ bo ni asiri ni, ko si ẹnikẹni ninu ile, gbogbo ayalegbe oun to ti jade lọ, wọn ko si tii wọle pada, ti ọkùnrin to muti yo naa si fi tipa wọnu yara oun.
"Aladugbo mi ti mo mọ ni ọkùnrin, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn naa, o fi tipa-tipa wọ yara mi lasiko to mu ọti yo ni aago mọkanla alẹ, o bo mi ni ẹnu, ki n ma baa pariwo, o si fi ipa ba mi ni ajọsepọ."
"Mo ja fita-fita amọ apa mi ko ka, o ṣe nnkan to fẹ ṣe, nigba to ya, mo raye pariwo sita, awọn aladugbo de, ti wọn si ko ẹgba bo o lẹyin, ko to fi mi silẹ."
Mama agba ni wọn ti fi iṣẹlẹ yii to agọ ọlọpaa to wa ni Agbado leti, tawọn ọlọpaa si ti mu afurasi ọhun, bakan naa ni wọn ba aṣọ ati ina tọọsi to fi silẹ ni yara iya agba naa.
- Wàhálà tí àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àt'àwọn ẹgbẹ́ ìjayà míràn ń dá sílẹ̀ láwọn ọgbà fásitì Nàìjíríà
- ₦35,000 ni mò ń gbà bíi Adelé ọba, kò sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ - Adelé Olúbọ̀rọ̀pa
- Ìlú yóò le, ọmọ le kú, àìsàn yóò pọ̀ bí eégún kò bá jáde nílùú Ibadan - Olóòlù
- Jesu Oyingbo rèé, pásítọ̀ tó láṣẹ ìbálòpọ̀ lóri ọmọ ìjọ obìnrin