IGP Adamu: Pẹsẹ́ ní Ọlọ́pàá Naijiria wà látàrí ìṣekúpani Ọ̀gágun Iran

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọga ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu ti kesi ileeṣẹ ọlọpaa kaakiri lati wa ni pẹṣẹ lati koju ipenija kankan to ba yọju si wọn.

Eyi ko ṣẹyin bi Adamu sẹ fi lede wi pe o ṣeeṣe ki awọn ọlọlufẹ ọgagun orilẹ-ede Iran, Qassem Soleimani to wa labẹle fẹ da rogbodiyan silẹ, lẹyin ti orilẹ-ede Amerika ṣekupa ọgagun naa.

Ọga agba ọlọpaa naa fi lede ni oju opo ikansiraẹni Twitter lori iwadii ti iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ gbe jade

Opin ọsẹ yii ni orilẹ-ede Amerika fi ibugbamu oloro pa ọgagun naa lori ẹsun pe o ti pẹ ti ọgagun naa ti n wa nidi iṣekupani awọn ọmọ ilẹ Amerika.

Ọga ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, Mohammed Adamu naa wa pasẹ fun kọmisọnna ọlọpaa ati awọn ọga ọlọpaa ni ẹkun kọọkan lati wa ni pẹsẹ lati koju awọn eniyan to ba fẹ fa rogbodiyan.

Bakan naa ni Adamu fi da awọn ara ilẹ okeere to wa ni Naijiria lati ma bẹru nitori nitori wi pe aabo to peye yoo wa fun wọn.