Yoruba language: Ọdún 2020 to wọlẹ́ dé yìí á tu gbogbo wa lára

Eni ba laya to tó ọkunrin ko fi ami si ori gbolohun adura yii.

A ku ewu ọdun tuntun, ọdun 2020 a san gbogbo ẹyin ololufẹ BBC si owo, ọmọ, aiku balẹ ọrọ ati alaafia.

Eledumare a jẹ ki ọdun tuntun yii yabo fun gbogbo wa.

Ọdun a yabo jẹ gbolohun adura ti ọpọ maa n lo ni ibẹrẹ ọdun tuntun lati fi ki ara wọn nilẹ Oodua.

Ki ede Yoruba le tubọ maa gbooro ni BBC Yoruba ṣe jade lọ ni ki awọn eeyan fi ami si gbolohun adura naa.

Akọ duro fun ọkunrin, o tun duro fun nkan to le bii okuta nigba ti abo duro fun obinrin ati nkan to mu ọwọ ẹrọ dani.

Idi ni yẹn ti awọn eeyan fi maa n sọ pe ọdun tuntun a ya abo to tumọ sipe nkan a rọ gbogbo wa lọrun.

Idahun si ibeere yi ni:

Ọdun a ya abo - re mi mi re re re

Ọdun a yabo - re mi mi re re