Premier League: Southampton dáná sun Stamford Bridge pẹ̀lú àmì ayò 2-0

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ Southampton fẹyin Chelsea gbolẹ nile wọn ninu idije Premier League to waye lonii.
Iya ti Chelsea jẹ lonii ko ṣẹyin akitiyan Micheal Obafemi ati Nathan Redmond ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye ni papa iṣere Stamford Bridge.
Micheal Obafemi lo kọkọ dana sile Chelsea ninu abala kini ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni Redmond naa sọ goolu tirẹ sinu awọn.
Bo tilẹ jẹ pe Chelsea ṣe bi okunrin, to si gbiyanju lati ri ẹyin awọn Southampton, ṣugbọn ko lee ta putu.
Ni bayii, ikọ Chelsea ti wa ni ipo kẹrin lori tabili lẹyin to n tẹle Manchester City lẹyin.










