You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Independence Day: Ẹ wo kókó àwọn ọrọ́ tí Aàrẹ Buhari sọ ní October 1
Aarẹ orilẹ-ede Naijiria ti kesi awọn ọmọ Naijiria sọra fun iwa radarada ti ko ba ofin mu, ki iyipada, ‘change’ le waye.
Aarẹ Buhari sọ eyi lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ni Ọjọ Ayajọ Ominira orilẹ-ede Naijiria (Independence Day) ni Ọjọ Kinni, Osu kẹwaa, ọdun 2019.
Buhari ni iyipada orilẹ-ede Naijiria ko le e waye, ti awọn ọmọ Naijiria ko ba fi ọwọsọwọpọ pẹlu ijọba lati mu Naijiria de ilẹ ileri.
Bakan naa lo fi kun un wi pe ibọwọ fun ara wa gbọdọ jẹ awọn ọmọ Naijiria logun fun itẹsiwaju orilẹ-ede Naijiria.
Amọ, Aarẹ Buhari ko sọ nipa gbigbogun ti iya ati isẹ ati eto rẹ lati koju wahala awọn Fulani darandaran lorilẹ-ede Naijiria.
Koko awọn ọrọ ti Aarẹ Buhari sọ ni October 1:
- Eto aabo: Ijọba n ra awọn ohun ija fun ileesẹ ọmọ ogun Naijiria lati le sisẹ takuntakun ti yoo fi opin si Boko Haram ati eto aabo to dẹnukọlẹ lorilẹ-ede Naijiria.
- Iwa jẹgudujẹra: Aarẹ Buhari ni igbogunti iwa jẹgudujẹra ti sọ eso rere pẹlu bi awọn ti se ri ọpọlọpọ owo gba pada lọwọ awọn ọbayejẹ lawujọ.
- Opopona Ibadan si Eko: Aarẹ Buhari ni awọn yoo pari gbogbo atunse ti awọn n se ni oju ọna marosẹ Ibadan si Eko ati ọkọ oju irin ni ọdun 2022, pẹlu awọn ọna miran ti wọn n se kaakiri Naijiria.
- Ina ọba: Bakan naa ni Aarẹ ni ayipada yoo de ba eto ina nitori pe awọn ti bẹrẹ si ni mu imugbooro ba ina ọba lati 5 Gigawatts si 7 Gigawatts, ati 11 Gigawatts ni odun 2023.
- Eto ọgbin: ipese owo fun awọn agbẹ lati le e mu isẹ agbẹ lọkunkundun yoo tẹsiwaju, ki eto ọgbin le gbooro si ni Naijiria.
- Ileesẹ Ọlọpaa: Aarẹ ni awọn ti bẹrẹ iyipada ni ẹka ileesẹ ọlọpaa, lati pese fun awọn ọlopaa, ati ohun gbogbo ti wọn nilo lati mu eto aabo labẹle gbooro si.
- Ole jija lori ẹrọ ayelujara: Igbogun ti awọn ti wọn n jale lori ẹrọ ayelujara ti n sọ eto rere, bẹẹ ni Aarẹ wa parọwa si awọn ti wọn n hu iwa bẹẹ lati jawọ nitori owo sinku ijọba ko ni pẹ ẹ mu wọn
- Sisọ oro kubakugbe lori ẹrọ ayelujara: Aarẹ Buhari ni awọn ọmọ Naijiria gbọdọ bọwọ fun ara wọn, paapaa lasiko ti wọn ba n fi ẹhọnu han lori nkan ti ijọba n se ti ko tẹwọnlọrun.
- Ọpa epo rọọbi orilẹede Naijiria: Bakan naa ni ijọba n pese eto aabọ fun awọn ọpa epo lorilẹede Naijiria lati le e mu imugbooro ba eto epo rọọbi orilẹede Naijiria, eleyii ti Aarẹ Buhari sọ wi pe oun mu owo wọle fun orilẹede naa.
- Eto pipa owo wọle fun Naijiria: Aarẹ Buhari ti ni awọn ti bẹrẹ si ni gbogun ti awọn ti kii san owo ori wọn, eleyii ti o n dena bi owo se n wọle si apo ijọba.