#StopRobbingUs: Ilé-isẹ́ ọlọ́pàá Naijiria gbọdọ̀ jáwọ́ nínú ìfìyajẹni

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn eniyan jankan-jankan ni ẹka imọ ẹrọ lorilẹ-ede Naijiria ti da owo jọ pọ lati gbe ile isẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria lọ si ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn n fi iya jẹ wọn lọna aitọ.

#StopRobbingUs ni wọn n lo lati fi fi ẹhọnu wọn han lori ẹrọ ayelujara lori bi awọn ọlọpaa se n na wọn, ti wọn si n gba owo ni ọwọ wọn lọna aitọ.

Lati Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Kẹsan an, ni wọn bẹrẹ si ni ko owo naa jọ, ti wọn si ti ri owo to to miliọnu mọkanla Naira ($30,000) ni aarin ọjọ kan.

Ọkan lara awọn to n fẹhọnu han naa sọ bi ọrọ naa se bẹre pẹlu bi ajọ ileesẹ ọlọpaa ṣe bẹrẹ, bakan naa ni awọn miran si bẹrẹ si ni fi fidio bi awọn ọlọpaa se fi iya jẹ wọn lede.

Awọn to wa ni idi ifẹhọnu han naa wa kesi ijọba orilẹ-ede Naijiria ko tọwọ awọn ọlọpaa Naijiria bọsọ, nitori awọn ṣetan lati taatan pẹlu wọn.

Awọn eniyan yii ni wọn ni ẹri to pọ to n ṣafihan bi awọn agbofinro Naijiria ṣe maa n huwa aitọ si awọn eniyan nibikibi.

Gbogbo eniyan ni wọn n pe ni ọmọ Yahoo ti awọn ọlọpaa si n foju ole wo.

Titi di asiko yii, awọn agbofinro ko tii sọ nkankan lori awọn #StopRobbingUs ṣugbọn awọn eniyan agbegbe naa ni ajọ to n mojuto ẹsun awọn ara ilu ti bẹrẹ iwadii to yẹ.

Iroyin ni ileeṣẹ ọlọpaa ti mu awọn oniṣẹ ibi kan ni agbegbe H Command ni Ogudu to gba owo lọwọ ninu awọn to n kọminu yii.