Ọọni Ile-Ifẹ: Gbogbo olùdìbò ló ní agbára ti rẹ̀

Àkọlé fídíò, Ọọni Ile-Ifẹ: Gbogbo olùdìbò ló ní agbára ti rẹ̀.

Ibi àgbà ni á n bá àgbà. Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi ti sọrọ lori eto idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Ọsun.

Ọba Ogunwusi nigba to n ba BBC sọrọ ṣalaye pe, ìmọ̀ àwọn eniyan lori agbara ti wọn ni gẹgẹ bii oludibo ti pọ sii.

Lasiko Ọdun Ọlọjọ ni Kabiesi fi ye wa pé awọn ọmọ Naijiria ni agbara lati yan ẹni to wu wọn, ti wọn rò pe o maa yi igbe aye wọn pada si bi wọn ṣe fẹ lasiko idibo.

Oni ọjọ kinni, oṣu kẹwaa ni eto ayẹyẹ ọdún ọlọjọ ti 2018 a pari pẹlu ijo ibilẹ loriṣiiriṣi.