Ọọ̀ni Ogunwusi: Irọ́ ni àhésọ pé mo ní olorì tuntun

Oríṣun àwòrán, Ooniadimulaife/Instagram
Ọọni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi ni ko si ootọ kan ninu ahesọ pe oun ti mu olori tuntun wọ aafin.
Ọmọọba Jide Fadairo to ṣe agbẹnusọ rẹ gbe atẹjade kan sita ni ọjọ Aiku ninu eyi to ti sọ pe ko ṣeeṣe ki oba naa mu iyawo ni ikọkọ.
O ni, "Kii ṣe idile ọba nikan ni yoo mọ si iru igbeyawo bẹẹ. Awọn aṣa ilẹ Yoruba gbudọ farahan ni iru igbesẹ bee. Oriṣiriṣi orukọ olori tuntun lati n gbọ, sugbọn ko si otitọ kan nibẹ."
Ẹ o ranti wipe, oṣu kẹjọ ọdun 2017 ni igbeyawo ọba naa f'ori sanpọn. O ti wa lai ni olori lati igba naa.









