Ó di gbéré, Ole lọ! Manchester United yọ Ole bí ẹni yọ jìgá gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá wọn

Ole Gunnar Solskjaer

Oríṣun àwòrán, Manchester United

Lẹyin ọ rẹyin, ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti le akọnimọọgba wọn, Ole Gunnar Solskjaer, lọ lẹyin ti Watford lu wọn ni alubami pẹlu ami ayo mẹrin si ẹyọkan ninu idije Premier League.

Man U fi ikede yii lede loju opo Facebook rẹ lọjọ Aiku.

Ẹgbẹ agbabọọlu naa ni o nira fun awọn lati le Ole danu amọ, awọn ni lati ṣe bẹẹ nitori nkan ko ṣẹnu 're fun Man U mọ.

Michael Carrick ni yoo maa ṣe akoso Man United bayii titi ti wọn yoo fi yan akọnimọọgba fidihẹ.