Cristiano Ronaldo: ''Ronaldo ṣì lè padà sí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Real Madrid''

Oríṣun àwòrán, Instagram/Cristiano Ronaldo
Ko le ja iyalẹnu ti agbabọjẹ agbabọọlu, Cristiano Ronaldo ba pada si ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid.
Akẹgbẹ Ronaldo ninu ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Portugal, Jose Fonte lo sọrọ yii nipa ẹlẹsẹ ayo, Ronaldo to wa pẹlu ikọ Juventus bayii.
O ni Ronaldo ma fi n fi aye a ti dagbere silẹ nibi kibi to ba wa lati pada si ẹgbẹ agbabọọlu to wa tẹlẹ.
Ronaldo fi Real Madrid silẹ lọ si Juventus lọdun 2018 lẹyin to ti ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu naa lorilẹede Spain fun ọdun mẹsan an gbako.
Ọgọrun un miliọnu pọn-un(£100million) ni Juve san fun Madrid ki Ronaldo to darapọ mọ wọn.
Lati igba ti Ronaldo ti wa ni Manchester United lo ti bẹrẹ si ni gba oniruuru ami ẹyẹ, ṣugbọn nigba to darapọ mọ Real Madrid lo gba oriṣiiriṣii ami ẹyẹ.
Cristiano Ronaldo ti gba gbajugbaja ami ẹyẹ Ballon d'Or fun igba marun un ọtọtọ, Lionel Messi nikan lo gba a juu lọ pẹlu mẹfa to gba.
Fonte ni Ronaldo si Madrid nitori o fẹran ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid pupọ, o ni bakan naa lo fi ọpọ awọn ọrẹ sibẹ.
Ronaldo si ni ọdun meji ṣii ninu iwe adehun to buwọlu pẹlu Juventus.












