Vincent Enyeama: Aṣọ́lé Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí ṣe tán láti padà sórí pápá

Oríṣun àwòrán, Instagram/Vincent Enyeama
Aṣọle fun ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri, Vincent Enyeama ti ṣe tan lati pada sori papa lẹyi ti ko ṣoju ikọ agbabọọlu kankan fun ọdun meji.
Enyeama wa pẹlu ikọ agbabọọlu ilẹ Faranse, Dijon nibi ti o ti n gbaradi fun ati pada sori papa.
Ẹgbẹ agbabọọlu Dijon fun Enyeama laye lati wa pẹlu wọn di ipari oṣu yii.
- Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò dágbére fáyé lẹ́yìn ìjà rẹ
- Transfer Window: Pogba, Maguire, Bale, Neyman, báwo ni nkan ṣe ń lọ?
- Ọlọ́pàá Kwara ti rí ọmọ orílẹ̀-èdè Turkey mẹ́rin gbà padà lọ́wọ́ ajínigbé!
- Ètò RUGA wọn kò lè ká Fulani 500,000 tó wà nínú igbó ilẹ̀ Yorùbá - Oluwo
- Alábàárù ni mò ń ṣe lọ́jà Ketu àti Mile 12, kí ń tó bẹ̀rẹ̀ Fuji - Atawẹ́wẹ́
Lẹyin naa ni akọnimọọgba Stéphane Jobard yoo gbe igbesẹ bo ya Enyeama yoo dara pọ mọ ikọ Dijon.
Ọdun 2017 ni aṣọle Enyeama ṣoju ikọ agbabọọlu kẹyin lẹyin to fi ẹgbẹ agbabọọlu Lille silẹ loṣu kẹjọ ọdun 2018.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Vincent Enyeama
Enyeama ṣoju ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ninu ifẹsẹwọnsẹ ọgọrun o le kan.
Bakan naa lo mu 'le fun Naijiria ninu idije AFCON marun un ko to fi ikọ agbabọọlu Super Eagles silẹ.
O wa lara ikọ agbabọọlu Naijiria to gba ife ẹyẹ AFCON 2013 lorilẹede South Africa.













