AFCON 2019 final: Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ Algeria là kìnìún Senegal mọ́ lẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì gba ife

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikilọ kẹlẹgbẹ mẹgbẹ rẹ ni ẹgbẹ agbabọọlu Algeria fi ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON 2019 ṣe fun ikọ Senegal lẹyin ti wọn rọ ojo iya le wọn lori lẹẹkeji ti wọn si gba ife ẹyẹ AFCON mọ wọn lọwọ.
Lẹyin iṣẹju meji pere ti ere bọọlu naa bẹrẹ ni ọkan lara awọn agbabọọlu Algeria, Baghdad Bounedjah gba goolu aramọnda kan wọ le, eyi to mu Algeria siwaju.
Bo tilẹ jẹ pe ogbontarigi adilemu fun Senegal, kalidou koulibaly ko lanfani lati kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun nitori o ti gba kaadi olomi ọsan(yellow card) meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta, ikọ Senegal ṣi ja fitafita isbẹsibẹ.
- Ta ni agbábọ́ọ̀lù tó fakọyọ jù lọ ní Afcon 2019?
- Ẹyẹ j’ẹyẹ lọ! Super Eagles f'ìyẹ́ bo Carthage Eagles Tunisia mọ́ 'lẹ̀
- Àjọ CAF gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Amaju Pinnick
- Afọnja, ẹni tó finú wénú ní Ilọrin, àmọ́ tó jẹ iwọ
- OPC kò láṣẹ láti fipa lé ẹ̀yà kan nílẹ̀ Yorùbá lórí ọ̀rọ̀ ikú Olakunrin- Ọlọ́pàá
- Tí kìí bá ṣe ti Barrister, iṣẹ́ ‘Gateman’ ni ń bá máa ṣe - Ayinla Kollington
Ilumọọka agbabọọlu Liverpool, Sadio Mane ati awọn akẹgbẹ gbiyanju agbara wọn lori papa, ṣugbọn awọn agbabọọlu Algeria duro wamuwamu bi ologun ti wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igba keji ree ti Algeria yoo gba ife ẹyẹ AFCON lẹyin ti wọn gbaa fun igba akọkọ lọdun 1990.
Bakan naa, igba keji ree ti ẹgbẹ agbabọọlu Senegal yoo gba ipo keji(fadaka) ninu idije AFCON lẹyin ti wọn kọkọ gbaa lọdun 2002 nigba ti wọn gbalejo idije naa.








