AFCON 2019: Òde kò dùn fún super Eagles, Madagascar nà wọ́n pẹ̀lú 2-0

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nkan ko ṣẹnu're fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti Naijiria ni abala akọkọ ati ikeji idije wọn pẹlu akẹẹgbẹ wọn lati orilẹede Madagascar.
Ami ayo meji soodo ni Madagascar fi fi ẹyin Super Eagles janlẹ.
Igba akọkọ niyi ti ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar n kopa ninu idije Afcon. Lori atẹ igbelewọn ajọ to n mojuto bọọlu l'agbaye, ipo kejidinlaadọfa ni Madagascar wa ti Naijiria si wa ni ipo kejilelogoji.
Ẹgbẹ agbabọọlu kankan ko ti i bori Madagascar lati igba ti Afcon 2019 ti bẹrẹ. Wọn ti dije lẹẹmẹta.
Lọwọlọwọ, ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar lo wa ni oke tente atẹ igbelewọn ninu idije Afcon 2019.
Bawo ni imurasilẹ Super Eagles ṣe ri?
Idije AFCON to n lọ lọwọ ni orilẹ-ede Egypt ni Naijiria ti koju Madagascar ninu ipele ẹgbẹ ti wọn yoo fi bọ si ti ẹni mẹrindinlogun.
Akọnimọọgba Naijiria ni eyi tumọ si pe Ola Aina àti Chidozie Awaziem lo máa di ẹ̀yìn ilé mú nínú ìdíje òní.
Rohr ni oun ni idaniloju pe awọn adiẹyin mu mejeeji yii yoo wulo ninu idije ipele ẹlẹni merindinlogun ti o m bọ lọna.
O ni oun yọ awọn mejeeji nitori pe wọn fi ara pa ṣaaju idije to kọja.
Rohr ṣalaye fawọn oniroyin pe Collins ati Shehu ti n gba itoju to yẹ.
Gernot Rohr, akọ́nimọ̀ọ̀gbá Super Eagles ti ni Ola Aina àti Chidozie Awaziem lo máa di ẹ̀yìn ilé mú nínú ìdíje òní.
O ni oun mọọmọ yọ wọn ninu idije toni ni ki wọn le sinmi ati pe Naijiria ni awọn agbabọọlu to pé to lati koju Madagascar.

Oríṣun àwòrán, others
Ta ni Madagascar n Naijiria ti gbena woju nirọlẹ yii?
Barea to ṣafihan agbara Madagascar ni orukọ inagijẹ ẹgbẹ agbabọọlu Madagascar ti Naijiria n koju loni.
Ikọ Agbabọọlu yii ko kopa ri ninu idije ifẹ ẹyẹ agbaye.
Igba akọkọ ti wọn n kopa ninu idije AFCON tilẹ Adulawọ ni ti 2019 to n lọ lọwọ ni Egypt.
Orilẹ-ede Madagascar ko kopa ninu idije FIFA lati ọdun 1950 si 1970.
Lodun 1974 ti wọn fẹ kopa ni wọn tun yọwọ ninu idije.
Wọn gbiyanju lọdun 1982, 1994, 1998, 2002, 2006, 2010, 2014, ati 2018 ṣugbọn wọn ko jawe olubori lati le kopa ninu ife ẹyẹ agbaye.
Orilẹ-ede Madagascar ko jawe olubori lati kopa ninu idije AFCON ri.
Lọdun 2000, 2002, 2004, 2006, 2008, 2010, 2012, 2013, 2015, 2017 ti wọn gbiyanju ẹ ni wọn ko ti bori lati dije rara.
Madagascar ninu idije AFCON 2019:
Omi ayo meji si meji ni Madagascar ati orilẹ-ede Guinea gbá ni papa iṣere Alexandra ni Egypt to n gbalejo AFCON.
Ojo kejilelogun, oṣu kẹfa ni idije naa waye.
Bakan naa ni Madagascar ti gbena woju orilẹ-ede Burundi ninu idije to n lọ lọwọ yii.
Ni eyi ti wọn ti fun Burundi ni ami ayo ookan si odo lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa.
Loni ni wọn yoo koju Super Eagles Naijiria lati mọ ẹni ti agbara wa lọwọ rẹ.
Awọn agbabọọlu Madagascar ti ni ki Naijiria ma foju rena awọn nitori pe awọn ko wa ta guguru ninu idije AFCON to n lọ lọwọ ni Egypt.

















