You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
The 27th Anniversary: Ò ti pé ọdún 27 tí Shah Rukh Khan ti ń se fíìmù India
Ọdun mẹtadinlọgbọn ni yii ti Shah Rukh Khan to jẹ gbajugbaja oṣere to máa n dari bi fiimu ti bẹrẹ isẹ ni ẹka amuludun.
Ọpọlọpọ eniyan lo mọ Shah Rukh Khan gẹgẹ bi gbajugbaja osere to ma n se fiimu ololufẹ ni Bollywood.
Lori ẹrọ ayelujara, awọn ololufẹ rẹ ti n ki i pẹlu #27GoldenYearsOfSRK (Shah Rukh Khan Guide at 27 years) lati ki ku oriire.
Lara awọn ololufẹ rẹ sọ wi pe nitori nigba ti Shah Rukh Khan de agbo osere Bollywood ni bi ọgbọn sẹyin ni ohun gbogbo yipada fun ẹka fiimu awọn India.
Shah Rukh Khan to jẹ Musulumi ni awọn ololufẹ kaakiri agbaye, ti ọpọlọpọ miliọnu eniyan si n tẹle e lori awọn ẹrọ ikansiraẹni.