You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Premier League: Man City fìyà jẹ Cardiff láti padà sókè téńté
Manchester CIty ti pade sipo kinni ninu idije Premier League lẹyin ti wọn fiya jẹ Cardiff City pẹlu ami ayo meji sodo.
Liverpool to wa loke tente tẹlẹ lo ti wa nipo keji ti Man City si n fi ami ayo kan siwaju.
Lẹyin iṣẹju marun un pere ti wọn bẹrẹ ere bọọlu ọhun ni agbabọọlu Man City Kevin DE Bruyne gbayo wọle Cardiff ti City si bẹrẹ si leke.
Agbabọọlu iwaju Leroy Sane fọba lee fun ikọ Man City pẹlu goolu keji nigba ti o ku iṣẹju kan ki ipele akọkọ pari.
Man City yoo gbami ẹyẹ idije Premier League ti wọn ba le jawe olubori ninu gbogbo ifẹṣẹwọnsẹ mẹfa to ku fun wọn lati gba ni saa yii.
Ẹwẹ, ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ miran, Tottenham dawọọ papa iṣere tuntun lẹyin ti wọn na Crystal Palace pẹlu ami ayo meji sodo.
Chelsea naa fakọyọ nigba ti wọn pokọ iya fun Brighton pẹlu ami ayo mẹta sodo.