CAF Awards: Mo Salah gbà àmì ẹ̀yẹ agbábọ́ọ̀lù Áfíríkà fún ìgbà kejì

Agbabọọlu Liverpool, Mohamed Salah ni agbabọọlu ajọ Confederation of African Football Player of the Year fun ọdun 2018. Igba keji si re e to gba ami ẹyẹ naa lera-lera.

Salah, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn fi ẹyin akẹgbẹ rẹ ninu ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Sadio Mane ati ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal to wa lati Gabon, Pierre-Emerick Aubameyang, janlẹ ninu ifigagbaga fun ami ẹyẹ naa.

Ọjọ Iṣẹgun lo gba ami ẹyẹ naa nibi eto kan to waye l'orilẹede Senegal.

Salah ti kọkọ gba ami ẹyẹ BBC African Footballer of the Year fun igba ẹkeji.

Agbabọọlu orilẹede South Africa, Thembi Kgatlana lo gba ami ẹyẹ gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin to tayọ ju ni Afrika.

Salah gba bọọlu sinu awọn fun Liverpool ni igba mẹrinlelogoji ni saa idije bọọlu gbigba 2017/2018, eyi to fi mu ko ṣeeṣe fun ẹgbẹ agbabọọlu naa lati de ipele aṣekagba idije Champions League.

Bakan naa lo gba bọọlu sinu awọn fun orilẹede rẹ, Egypt lẹẹmeji lasiko idije ife agbaye to waye ni Russia.

Ẹwẹ, o ti gba bọọlu sinu awọn fun Liverpool ni igba mẹrindinlogun lasiko mọkandinlọgbọn to ti kopa ninu idije ni saa yii.

Awọn agbabọọlu miran to ti gba ami ẹyẹ naa lera

Yaya Toure ọmọ orileede Ivory Coast ti o fi igba kan jẹ agbaaarin fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City lo ṣi yi gba ami ẹyẹ naa lerawọn lẹẹmẹrin laarin ọdun 2011-2014.

Samuel Eto'o ọmọ Cameroon naa gba ami ẹyẹ naa lẹẹmẹrin ṣugbọn kii ṣe lerawọn.

O gba ni ọdun 2003-2005 o si tun gba pada ni ọdun 2010.

Orileede rẹ, Cameroon lo gba ami ẹyẹ naa julọ; wọn gbaa ni igba mọkanla.

Ivory Coast tẹle pẹlu gbigba ami ẹyẹ naa lẹẹmẹjọ, Ghana lẹẹmẹfa, ti Naijiria si gba ni igba maarun.