SARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro níṣẹ́
Kọmiṣọna fun ọlọ́pàá kògbérégbè sọ̀rọ̀ lórí àtúntò to ti wọ iṣẹ SARS.
Ọgbẹni Haliru A. Gwandu to n tukọ ajọ ọlọpaa kogberegbe ni Naijiria ṣalaye kíkun lori iṣẹ tijọba gbe fun un lati bẹrẹ atunṣe si ajọ SARS.
O ni iṣẹ atunṣe naa ti bẹrẹ bayii.
Kọmiṣọna naa ni ofin ti de awọn ọlọpaa kogberegbe lasiko yii nitori pe wọn kò gbọdọ kọja aala wọn mọ.
O ni idigunjale, jijinigbe, ipaniyan, ẹgbẹ́ okunkun ni koko pataki ohun tijọba fẹ ki SARS fopin si lawujọ.
