'Mi ò ní wo bọ́ọ̀lù mọ́ ti Nàìjíríà bá fìdírẹmi ni Russia 2018'

Àkọlé fídíò, 'Mi ò ní wo bọ́ọ̀lù mọ́ ti Nàìjíríà bá fìdírẹmi ni Russia 2018'

Ìdíle Adeṣẹmọwọ ni kò si ìjà lórí rìmóòtù mọ́ titi ti Russia 2018 yóò fi parí.

Abilekọ Ọlayẹmi James Adeṣemọwọ gba pe òun kò ni wo telemundo ati Zee world ti òun fẹran julọ lasiko ìdíje ife ẹyẹ agbaye.

Oun ati awọn ọmọ rẹ mẹtẹẹta ni wọn ti yọnda ohun èèlo ti a fi n dari eto ti a n wo lori amohunmaworan, rìmóòtù, ile wọn fún ọkọ rẹ̀ lati fi wo idije World Cup 2018 to n lọ lọwọ ni Russia.

Awọn ọmọ rẹ naa, Gabriella, Mark ati Simon, ni àwọn kò ni wo 'Cartoon' ati 'PJ max' ti awọn fẹran julọ ki baba wọn, Ọgbẹni James le ṣatilẹyin to yẹ fun Super Eagles.

Ọgbẹni James to jẹ baale ile ọhun ni oun féran lati maa gbọ iroyin ati lati maa wo bọọlu ni eyi ti awọn to ku kò fẹran ṣugbọn inu oun dun pe ẹbi oun ti gbagbọ ninu Naijiria pe, Super Eagles a de ipele keji to kangun si aṣekagba ni Russia.

Amin iyasọtọ kan