World Cup 2018: Ronaldo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lu Spain ni Russia

Ife ẹ̀yẹ àgbáyé nìkan ló kù fún Christiano Ronaldo lati gba.

Gbajugbaja agbabọọlu jẹun ni, Christiano Ronaldo, yoo bẹrẹ irinajo idije ife ẹyẹ agbaye eleyi ti o ṣeeṣe ko jẹ agbagbẹyin rẹ nigba ti orilẹ-ede Portugal ba n koju Spain lọjọ Ẹti.

Ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni yoo jẹ akọkọ fun orilẹ-ede mejeeji ti wọn múlé ti ara wọn yii nibi idije ife ẹyẹ agbaye to bẹrẹ lorilẹ-ede Russia l'ọjọbọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọmọ ọdun mẹtalelọgbọn ni Christiano Ronaldo bayii, o si daju pe mẹfa ninu awọn akẹgbẹ rẹ ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid lo ṣeeṣe ko ba pade lasiko ifẹsẹwọnsẹ naa.

Bakan naa, awọn agbabọọlu orilẹ-ede Spain yoo maa gbiyanju lati fi iṣẹlẹ olukọni wọn, Julen Lopetegui, ti wọn yọ nipo laipẹ yii, sẹyin bi egungun ṣe n fi aṣọ.

Gbogbo ami idanilọla ti agbabọọlu jẹun lee gba lorilẹ aye ni Christiano Ronaldo ti gba, ayafi ife ẹyẹ agbaye.

Ọkan lara awọn akẹgbẹ rẹ ni ikọ agbabọọlu Portugal, Joao Mario sọ pe, 'Ko si aniani pe Ronaldo ni agbabọọlu to pegede julọ lagbaye bayii, yoo si wa lara awọn wọ-kilu-mọ agbabọọlu ti yoo maa da bira ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti ọtẹ yii.'