Aṣọle Tunisia fi ọgbọ́n já ààwẹ̀ Ramadan ki wọ́n lè borí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọgbọ́n kìí tán láyé ká wáa lọ s'ọrun

O dífá fún aṣọle ìkọ agbabọọlu orílè-èdè Tunisia, Mouez Hassen, tó dá ọgbọn ki awọn akẹgbẹ re ba le sinu àwẹ̀.

Nínú àwọn ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ tí wọn n gbà nínú ààwẹ̀ yí lo ti dogbon alumokoroyi ki awọn akẹgbẹ rè báa lè fí nkan tẹnu lasiko ti idije naa ba n lo lọwọ.

Bí àsìkò iṣinu bá tí tó, niṣe ní yóò ṣebi ẹni dákú kí àwọn akẹgbẹ rè lè sáré lọ sí ẹgbẹ kàn orí pápá ló fi èso tàbí omi já àwẹ̀ wọn.

Ọgbọn tó dá yí sí so èso rere.

Nínú ifẹsẹwọnsẹ Tunisia pẹlú Portugal, ó da ọgbọn yi nígbà tí Portugal n fi àmì ayo méjì sàgbà wọn.

Iṣẹju mẹfa lẹyin igba ti Mouez Hassen ṣebi ẹni dákú ti awọn akẹgbẹ rè sí fí nnkan tẹnu ni wọn da ayo kan pada ti ifẹsẹwọnsẹ náà sì parí pẹlú ọmi ayo méjì.

Fídíò ìṣẹlẹ náà ti gba orí afẹfẹ lẹyìn tí ololufẹ eré bọọlu kan fi sita.

Lẹyìn ọjọ mélòó kan ti won tun kojú Turkey, Hansen tun ṣé bẹẹ dákú ti àwọn akẹgbẹ rè tún fí anfàní náà tù ẹnu fún ààwẹ̀.

Abajade kan náà ni ifẹsẹwọnsẹ náà bí.

Ọmi ayo méjì méjì ní wọn tún gbà.

Ṣé lootọ ní àbí o n dibọn?

Mouez Hassen ti fèsì sí ọrọ yi lójú òpó Twitter rẹ ni ìdáhùn sí ọrọ ẹ̀fẹ̀ ti akẹgbẹ rè Chaker Alhadur, fi sita pé "kò sí wàhálà, o yé wà pé o n dibọn ní"

O kọ ó síbẹ pé ''Mo ṣeṣe ní o!''

Nibayii awon èèyàn yóò fojú sí aṣọle náà lára nígbà tí Tunisia bá kojú Spain nínú ifẹsẹwọnsẹ tí yóò wáyé lọjo kẹsán oṣù kẹfà

Ifẹsẹwọnsẹ àkọkọ Tunisia ni idije àgbáyé yóò wáyé lọjo kejidinlogun, oṣù kẹfà.

Ààwẹ Ramadan yóò ti parí nígbà náà.