Ileesẹ ologun Naijiria: A mu afurasi Boko Haram mẹrin

Awọn afurasi ọmọ ikọ Boko Haram ti ọwọ awọn ologun tẹ

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Boko haram ti n sọsẹ lẹkun ariwa orilẹede Naijiria fun igba diẹ

Ọwọ awọn ologun ti tẹ afurasi kan lara awọn ikọ Boko Haram nileto Kalaa nijọba ibilẹ Hong nipinlẹ Adamawa.

Awọn afurasi naa wa lara awọn tileesẹ ologun fi orukọ wọn sita pe wọn jẹ asiwaju ikọ Boko Haram.

Awọn ologun ni ọwọ tẹ afurasi naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Bubayi Isa, to wa lati ileto Panama lagbegbe Gunda nijọba ibilẹ Biu nipinlẹ Borno, lẹyin ti eeyan kan ta wọn lolobo nipa rẹ.

Amin iyasọtọ kan

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Amin iyasọtọ kan

Bakannaa ni wọn tun salaye wipe afurasi ọhun ti jẹwọ ara rẹ pe lootọ loun wa pẹlu ikọ adukukulaja Boko Haram, ti oun si ti kopa ninu ọpọlọpọ awọn ikọlu ti wọn ti gbe se.

Awọn ologun pẹlu ọkọ ijagun wọn

Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

Àkọlé àwòrán, Iwadi ileesẹ ologun tun sisọ loju rẹ pe orukọ afurasi naa wa lara awọn ti wọn ti n wa fun ọjọ pipẹ

Iwadi ileesẹ ọmọogun tun yọju rẹ sita wi pe orukọ afurasi naa, Burayi lo wa ni ipo kẹtadinlogoji ninu akọọlẹ awọn afurasi ti olu ileesẹ ologun lorilẹede Naijiria fi sita saaju asiko yii.

Awọn afurasi miran ti ọwọ awọn ologun tun tẹ ni Muhammad Buba ati Abdullahi Abubakar ti wọn wa lati agbegbe kan naa pẹlu Yakubu Abdullahi to wa lati Sabon Gari Gado nipinlẹ Borno.