You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Arsene Wenger: Idi tawọn ololufẹ Arsenal se nfi we Mugabe
Ọpọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ Arsenal lori opo ikansiraẹni Twitter loju opo itakun agbaye, ni wọn ti ngba oniruuru ọna alumọkọrọyi lati beere pe ki opin de ba akoso ọdun mọkanlelogun Arsene Wenger.
Bakanaa lawọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal tun nse afiwe Wenger pẹlu aarẹ orilẹede Zimbabwe ti wọn yọ nipo laipk yii, Robert Mugabe.
Bi o tilẹ jẹpe ọpọ igba lawọn eeyan maa nfi ọrọ yii sere laarin ara wọn tẹlẹ, amọ o dabi ẹnipe awada lasan yii ti fẹ di ootọ ni kete ti ẹgbẹ agbabọọlu Brighton gbo ewuro soju Arsenal pẹlu ami ayo meji si ọkan lopin ọsẹ.
Bẹẹni ẹnu ko tun sin lara Wenger saaju ifẹsẹwọnsẹ Arsenal pẹlu AC Milan eyiti yoo waye lọjọbọ ninu idije Europa League.
Lẹyin ọdun mẹtadinlogoji lori ipo aarẹ, wọn kan nipa fun Mugabe lati fi ipo naa silẹ lorilẹede Zimbabwe losu kọkanla sdun to kọja, ti ọpọ ololufẹ ere bọọlu si nfi Wenger se afiwe Mugabe nitori isẹlẹ yii.