Seaside Cottage Theatre Bariga: Ṣeun Awobajo sọ ìwúrí rẹ̀ tó fi ń kọ́ àwọn ọmọdé níṣẹ́ẹ Tíátà
Bi ẹ ba mọ ilu Bariga nipinlẹ Eko daadaa, ẹ o kan sara si ẹni ti o ṣaṣeyọri lati ko awọn ọmọde to yẹ ki wọn maa ṣe iwa ipa jọ ṣugbọn to n kọ wọ ni iwa ire pẹlu iṣẹ ọpọlọ Tiata.
Awọn ọmọ ti ko ba ti kọ ikọkukọ torii pe ṣugbọn wọn wa di ọmọ to n mu inu obi dun.
Toripe awọn ọmọ yii gangan lo nifẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ Tiata Footprints of David, ẹ wo bi idunu ati ayọ ṣe n kun inu wọn ninu fidio yii.

Ọkan ninu awọn ọmọde naa sọ fun BBC Yoruba pe "boola ni mo maa n ṣa boola, mo maa lọ taa ki a le fi jẹun ṣugbọn igba ti mo ti darapọ mọ ẹgbẹ Tiata yii, aye mi ti yi pada".

Ọmọ kan tilẹ ni sọ nipa gbogbo ere itage ifọwọsowọpọ ti wọn ti lọ ṣe kaakiri orilẹede agbaye ti iya rẹ naa si ni oun o tilẹ lero pe ọmọ oun lee de ibi kankan lagbaye bi ko ṣe tori ere tiata yii.
Oludasilẹ ati adari ẹgbẹ Tiata Foot Prints of David to kalẹ si ilu Bariga nipinlẹ Eko, Seun Awobajo ṣipaya iṣẹ́ takuntakun ti wọn n ṣe lati kọ awọn ọmọ wẹwẹ niṣẹẹ Tiata pẹlu ilu, orin ati ijo lede Yoruba fun igbelarugẹ Aṣa.

Itan igbesi aye oun gan funrarẹ jẹ eyi to fọwọ tọ ni lọkan gidi gan. Ohun si lo mu ko gbero lati maa kọ awọn to n la iru nkan ti oun naa la kọja lẹkọ ati ohun to lee mu wọn bori iṣoro wọn.
O ni bi iṣẹ naa ṣe gbe awọn ọmọ naa kaakiri awọn orilẹede nla nla lagbaye, "o ti jẹ kawọn eeyan mọ pe iṣẹ tiata kii ṣe iṣẹ rederede".
Iwuri nla ni iṣẹ ti Seun Awobajo n kọ awọn ọmọde yii tori o ti gbe wọn pade awọn aarẹ agbaye, gomina, atawọn eeyan nla nla lawujọ. Lara awọn aworan wọn ree.