You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdájọ́ ikú ló yẹ gbogbo olóṣèlú tó bá jí owó ìlú kó - Aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun
Ọkan lara awọn aṣoju ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Kanmi Ajibola ti fi ọrọ sita pe idajọ iku lo yẹ fun awọn oloṣelu to n hu iwa jẹgudujẹra, pẹlu alaye wi pe iwa ibajẹ ti o ga julọ ninu gbogbo ohun to tako ofin Olorun ati iṣẹda eeyan ni ki awọn to di ọlọrọ nipasẹ lilu owo ilu ni ponpo ṣi maa wa laaye.
Ajibola ti o jẹ alaga ẹgbẹ awọn Amofin, NBA tẹlẹri, ti o si tun n ṣoju ẹkun idibo Oriade n'ipinlẹ Ọṣun ṣe alaye wi pe ọna kan ṣoṣo ti a le gba dẹkun bi awọn eeyan kan ṣe n ji owo ilu ko lorilẹede Naijiria ni lati fi idajo iku lele fun iru awọn ole bẹẹ.
Amofin naa fi erongba rẹ han ninu iwe alabala marun un kan ti o kọ ranṣẹ lọjọ kẹẹdogun oṣu kẹta ọdun yii, si aarẹ ile igbimọ aṣofin, Sẹnetọ Godswill Akpabio ati alakoso ile igbimọ aṣoju-ṣofin, Họnọrebu Tajudeen Abbas.
O fi ẹda iwe naa ranṣẹ si agbẹjọro agba lorilẹede Naijiria, agbẹjọro agba n'ipinlẹ Ọṣun ati adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Rt. Hon. Adewale Egbedun.
O tọka si iṣọri Ikẹrin(ẹsẹ ikinni) ati Ikẹta ofin orilẹede yii, gẹgẹ bii itọna fun ile igbimọ afin lati ṣe agbekalẹ awọn ofin ti yoo dẹkun iwa ibajẹ lorilẹede yii.
Ajibola fi kun ọrọ rẹ pe awọn orilẹede bii China, Indonesia ati Thailand ti ṣe agbekalẹ idajọ iku fun ẹnikẹni ti o ba ji owo ilu ko, eyii lo si mu ki eto ọrọ aje awọn ilu naa maa ru gọgọ sii, gẹgẹ bi alaafia, eto aabo ati idagboke ṣe n j'ọba.
O ni awọn ofin to n ri si iwa ibajẹ lọwọlọwọ bayii ni Naijiria ko ri ẹsẹ walẹ bi o ti yẹ, gẹgẹ bi o ṣe n gbarata wi pe ileeṣẹ kan to n ri si ọrọ ilẹ okere niluu ọba, "London Chatham House" fi idi rẹ mulẹ wi pe laarin oṣu kẹwaa ọdun 1960 si oṣu kẹwaa ọdun 2019, owo ti o le ni ẹẹdẹgbẹta Billiọnu Dollar($582bn) ni awọn adari orilẹede Naijiria ati awọn oṣiṣẹ ijọba ji ko.
Bakan naa ni ajọ mii to n ri si idagbasoke awujọ, 'Human Environmental Development Agenda (HEDA)' ṣe fi abajade iwadii wọn sita pe orilẹede Naijiria padanu N1.6trillion ati $825.7million si ọwọ awọn oniwa ajẹbanu laarin ọdun 1999 si 2022.
Ajibola ni idajọ iku nikan ni ọna abayọ bi Naijira yoo ba boriyọ ninu ọgbun iwa jẹgudujẹra.