You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí apààyàn mẹ́fà tó gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú Ọmọọba láti ṣekúpa Ọba alayé kan ní ìpínlẹ̀ Ogun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi agbenipa mẹfa ti gbinmọ lati ṣekúpa Ọba ni Ipinlẹ Ogun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbola Oyeyemi, ninu atesita to fi ransẹ si awọn akọroyin ni orúkọ awọn afurasi naa ni, Michael Ayodele, Monday Samuel, Ademola Mathew, Hammed Jelili, Ogundele Ojeh ati Sunkanmi Fadina.
Oyeyemi ni awọn gba ipe lati ọdọ Ọba GO Olukunle ti ilẹ Gbokoto ni ìjọba ibilẹ guusu Yewa ni dede ago mẹrin kọja isẹju diẹ pe awọn oníṣegun mẹfa fẹ ṣekupa oun ni aafin.
O ni kete ni awọn gbera lati lọ sí agbegbe naa, lẹyin iwadi, ọwọ sì tẹ àwọn mẹfa ni bi tí wọn sina bolẹ ni aafin
"Awọn ọlọpaa wọ iyaja pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii, tí ọwọ sì tẹ mẹfa larin wọn
"Ninu iwadi wá, awọn afurasi naa jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Eiye ni awọn. Wọn tun sọ fun Ileeṣẹ ọlọpaa pe ọmọ Ọba lo ransẹ pe awọn lati wa ṣekúpa Ọba nítorí ọrọ kan to fa rogbodiyan laafin pẹlu olorì.
Oyeyemi fikun pe ọmọ Ọba naa ti salo kuro niluu naa sugbọn iwadi lọ lọwọ làti ri pe ọwọ tẹ ọmọkùnrin naa