You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni yóò lọ, ta ni kò ní lọ? Àwọn wo ló gba ìwé ìpè síbi ìsìnkú Ọbabìnrin Elizabeth?
Isinku Ọbabìnrin ti yoo waye ni ọjọ Aje to mbọ yoo jẹ ọkan lara awọn ayẹyẹ nla nla ti awọn Oriade àtàwọn olóṣèlú eyi to si ti maa n waye ni UK lati ọpọlọpọ ọdun sẹ́yìn ti awọn Ọba ti n jẹ.
Iwe ìpè ti jade lọ kaakiri ni opin ọ̀sẹ̀ to kọja yii ti ireti si wa pe nkan bii ẹẹdẹgbẹrun adari orileede lagbaye àtàwọn eekan agbaye ti yoo lọ síbẹ̀.
Wọn ti ni ki awọn eekan yii ba ọkọ baalu wa si UK ti wọn yoo si lọ fi ọkọ nla ko gbogbo wọn lati West London.
Ni Westminster Abbey ni eto isinku naa yoo ti waye eyi to lee gba eeyan bii ẹgbẹrun meji o le ni igba.
Ohun ti a mọ nipa awọn ti yoo lo ati ti ko ni lọ sibi eto isinku ti aye yoo gbọ ti ọrun yoo si mọ yii niyii.
Awọn Idile Oye nilẹ Yuroopu
Awọn ara ile oye jakejado ilẹ Yuroopu, lara awọn ti ọpọlọpọ wọn jẹ ẹjẹ ati ibatan Ọbabinrin, wa lara awọn ti wọn n reti nibẹ.
Ọba ilẹ Belgium Philippe ati Olori rẹ Mathilde ti fọrọ sita pe awọn yoo wa nibẹ.
Bakan naa ni Ọba Willem-allexander ati iyawo rẹ, Ọbabinrin Maxima to fi mọ iya rẹ, Ọbabinrin Dutch tẹlẹ Ọmọba Beatrix.
Ọba Felipe ati ỌbOlori Letizia ti Spain naa ti tẹwọ gba iwe ipe fun eto isinku bẹẹ naa si ni titi de awọn idile Ọba ni Norway, Sweden ati Denmark.
Awọn Aarẹ Amẹrika
Ile ijọba Amẹrika ti fi ọrọ sita pe Aarẹ Joe Biden yoo lọ fun eto isinku naa pẹlu iyawo rẹ Jill Biden bo tilẹ pe a gbọ pe kii ṣe ọkọ bọọsi ni wọn yoo wọ lọ.
Ọpọ ọrọ lo ti n fa ọrọ jade boya Aarẹ Biden yoo pe ẹni to gbe iṣẹ lee lọwọ, Donald Trump
pe ko wa lara ikọ ilẹ Amẹrika ti yoo kọwọ rin lọ amọ iye aye ti wọn fun Amẹrika lee fihan pe o ṣeeṣe ki awọn aarẹ tẹlẹri ma lee lọ.
Amọ awọn eeyan n roo boya awọn aarẹ tẹlẹ kan ati awọn iyawo wọn ti gba iwe ipe to da wa fun awọn nikan paapaa Obama ati aya rẹ.
Awọn adari ajọ ọrẹdẹgbẹ Commonwealth
Awọn adari kaakiri latinu ajọ ọrẹdẹgbẹ eleyi ti Ọbabinrin ti dari fun gbogbo aye rẹ ni ireti wa pe wọn yoo wa nibẹ.
Olootu Australia, Anthony Albanese ti gba iwe ipe, Oloot New Zealand, Jacinda Ardern ati ti Canada, Justin Trudeau.
Olootu Bangladesh to ti wa lati ọjọ pipẹ, Sheikh Hasina ati Aarẹ Sri Lanka, Ranil Wickremesinghe naa ni iroyin ni wọn ti gba iwe ipe.
Amọ titi di asiko ti a kọ iroyin yii, Olootu India ko tii fi ọrọ sita boya yoo wa nibẹ.
Awọn Adari agbaye to ku
Lara awọn adari mii ni agbaye to tun ti ri iwe ipe gba ni Taoiseach Micheal Martin lati Ireland, Aarẹ Germany, Frank-Walter Steinmeier ati ti Italy, Segio Mattarella to fi mọ Aarẹ ajọ ilẹ Yuroopu, Aarẹ Ursula von der Leyen.
Bakan naa, aarẹ South Korea, Yoon Suk-Yeol ati Brazil, Aarẹ Jair Bolsonaro naa ti ni awọn yoo lọ.
Lara awọn ti ireti tun wa pe wọn yoo lọ ni Alayeluwa ti ilẹ Japan, Emperor Naruhito, Aarẹ Turkey, Recep Tayyip Erdoğan, ati ti France Emmanuel Macron.
Ko tii ye boya Aarẹ China Xi Jinping to jẹ pe igba yii ni yoo jẹ akọkọ to tẹ ita China latigba ti Covid-19 ti bẹrẹ yoo lọ fun isinku naa.
Awọn ti wọn ko pe rara
Ko si aṣoju lati Russia, Belarus tabi Myanmar ti wọn fiwe pe gẹgẹ bi akọroyin BBC, James Landale ṣe jabọ.
Gbogbo ibaṣepọ to dan mọran laarin UK ati Russia lo ti polukurukusu lati igba ti Russia ti kogun ja Ukraine eyi to ṣi n lọ lọwọlọwọ bẹẹ si ni agbẹnusọ kan fun Aarẹ Russia, Vladimir Puti sọ ni ọsẹ to kọja pe ko roo lati lọ sibi isinku naa.
Ikọlu ogun naa kọkọ bẹrẹ lati agbegbe Belarus nibi ti Aarẹ ibẹ, Aleksandr Lukashenko ti jẹ ọrẹ timọtimọ Aarẹ Putin.
Bakan naa ni UK ti mu adinku ba iṣesi wọn ni Myanmar lati igba ti ija ologun ti waye ninu Oṣu Keji ọdun 2021.