Mọ̀ síi nípa ìlànà ìsìnkú àwọn Orí adé ni Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí àti bí o ṣe yàtọ̀

Lẹyin ikede iku Ọbabinrin Elizabeth keji ni ọjọ kẹjọ, osu Kẹwaa, Ọdun yi.

Wọn ti kede awọn ọjọ fun idaro eyi ti yoo pari lẹyin ọjọ meje ti ẹto isinku Ọbabinrin ba pari.

Bayii ni awọn ilana aatele lati sin awọn ori ade papa julọ Ọbabinrin Elizabeth to papọ da laipe ni ilẹ Gẹẹsi.

Àwọn Asia Yóò Wà Sílẹ̀

Ọkan ninu oun akọkọ ti ijọba maa n se ni lati fa asia orilẹ-ede wa silẹ.

Asa yii ti bẹrẹ lati 17th century,

Asa yi bẹrẹ gẹgẹ bi ọla fun olori ọkọ ọju omi tabi Ọkan lara awọn oludari ọkọ oju omi, awọn akegbe ologbe naa yoo faa asia wale lati buola fun oga wọn to di oloogbe.

Lẹyin iku Ọbabinrin Elizabeth,Omooba Charles ọmọ re to dagba julọ logun ori itẹ gẹgẹ bi ọba,to si di Ọba Charles kẹta.

Gbogbo awọn Asia nilẹ Gẹẹsi ni yoo wa silẹ titi di ọjọ keji ti ẹtọ isinku Ọbabinrin ba waye iyẹn ni agogo mejo ọjọ keji lẹyin isinku.

Àṣà Ìbọn yìnyín

Ọkan ninu awọn asa to jemo eto ṣinṣin awọn Ọba ni asa ibọn yinyin.

Gẹgẹ bi itan awọn Ologun ilẹ Gẹẹsi, Asa yii bẹrẹ ni 15th century nibiti awọn ọkọ oju omi tin ma n kede ni ile ajoji pe awọn ko ba ija wa nitori awọn ti yin gbogbo ọta ibon wọn tan.

Ni Ọdun 1730,awọn Ologun ori omi maa n yin ibọn lati se ayajo awọn ọjọ ajodun wọn.

Wọn ti ṣe ayẹyẹ yiyinbo soke lati daro Ọbabinrin Elizabeth keji ati lati sayajo ifoba je Ọba Charles.

Ọjọ kesan osu kewa ọjọ keji Lẹyin iku Ọbabinrin Elizabeth ni ẹto yii waye ni London ni gbagan Hyde.

Àṣà Aago Lílù

Ijọ ilẹ Gẹẹsi maa lu agogo lọjọ keji lẹyin ti wọn kede iku Ọbabinrin Elizabeth.

Nilẹ Gẹẹsi, asa yii bẹrẹ lati 7th century gẹgẹ bi iwe itan ti venerable Bede kọ nipa Hilda Whitby.

Ọkan ninu awọn asa idile Ọba ilẹ Gẹẹsi ni lati lu agogo Sebastopol fun Windsor.

Ki Ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi to ku, agogo na ama dun lekan lodun lati ṣe iranti iku iya Oba ile Geesi to ku ni ọdun 2002.

Àṣà Ìkéde Làti Ààfin

Iwẹ ikede pẹlẹbẹ kan ni wọn yoo le mọ ẹnu ọna aafin lati kede awọn ẹto pataki bi igba ti a ba bi ọmọ ninu aafin ati igba ti ẹnikẹni ba ku ninu aafin.

Lati kede ibimọ ninu aafin iwe pẹlẹbẹ ni wọn yoo gbe si aarin ọna abawọ aafin, sugbọn lati kede iku, iwẹ pẹlẹbẹ na ni wọn yoo le mo ara ilẹkun abawo aafin.

Iku George kefa lodun 1952 ati George karun un lodun 1936 ni wọn tun kede bayii.