You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Queen Elizabeth: Àwọn ìgbà tí Ọbabìnrin ṣe àwàdà tó pa àwọn èèyàn lẹ́rìín rèé
Ọbabinrin Elizabeth Keji to jẹ Alayeluwa ilẹ UK fun ọdun to le ni aadọrin ṣe idari laarin oniruuru igba ati asiko to yọju yala asiko rere tabi asiko to buru ti ko fara rọ fun ilu.
Koda, wọn ti kọ akọsilẹ bi o ṣe gbudọ gbe igbe aye rẹ nita gbangba titi ti yoo fi wa loke eepẹ, lara rẹ si ni pe ki o ma ṣe rẹriin amọ ko si bi iru awọn ofin bayii ṣe le to, adamọ ẹni o le ma foju hande torinaa ni ọwọ igbẹyin aye Ọbabinrin, o fun wa ni itọwo iṣesi apanilẹrin ti eleduwa da mọ ọ ko to di pe o jẹ Ọlọrun nipe lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun.
Lasiko ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC lati ibẹrẹ ọdun yii, Duke ti ijọba ilẹ Sussex da iya-iya rẹ iyẹn Ọbainrin ya sọtọ pe "pipani lẹrin yii" gaa ni iwa adamọ rẹ to dara ju.
Onimọ nipa itan, Sir Anthony Seldon sọ pe tori pe ko tilẹ ki n ka ara tirẹ kun bi ohun to jẹ babara bẹẹ wa lara "ohun to da si aṣeyọri iṣejọba rẹ".
"Rirẹrin lati gbagbe ohun ti ko yẹ jẹ ọkan pataki lara ohun to n mu ni wa laaye. Onimọ itan, Robert Lacey naa sọ eyi ngba to n sọrọ ṣaaju iku Ọbabinrin Elizabeth !! lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun.
Ẹwẹ, wọnyii ni diẹ lara awọn igba ati akokoo dida ọwẹkẹ Ọbabinrin niyi ti araye si mọ:
Ẹ̀fẹ̀ bẹ́ silẹ̀ nibi Ayẹyẹ Jubile ti Queen ti n mu "tea" pẹlu "Paddinton Bear"
Gẹgẹ bi ọkan lara ayẹyẹ ọdun Platinum Jubilee ti Ọbabinrin ṣe ninu oṣu kẹfa to kọja yii, fọnran ri i to n mu tea pẹlu nibi ayẹyẹ ọhun eyi ti ileeṣẹ BBC ṣe ni Aafin rẹ lati ṣaami ayẹyẹ aadọrin ọdun to pe lori itẹ gẹgẹ bi ọba.
Nigba ti ayẹyẹ naa fẹ bẹrẹ, Paddington nawọ ipanu to fẹran ju sii iyẹn "marmalade sandwich". "Mo saba maa n ya ọkan sọtọ fun pajawiri", o sọ fun un to si n fa ọkan jade lati abẹ fila pupa to de sori.
"Emi gaan a maa ṣe bẹẹ", Ọbabinrin fesi bo ṣe n ṣi baagi apamọwọ dudu rẹ toun naa si fa ipanu tirẹ naa jade.
Ere Idaraya 'fighting talk'
Lọdun 2016, ṣe ni Ọbabinrin tun han ninu fidio kan to gba ori ayelujara kan - pẹlu ọmọ-ọmọ rẹ, Ọmọọba Harry ti wọn n ṣe ipolowo fun ere idaraya ti wọn n pe ni Invictus Games (fighting talk).
Awọn mejeeji wo fidio kan eyi ti Aarẹ US tẹlẹ ati iyawo rẹ, Barrack ati Michelle Obama ti pe Harry nija lori ere idaraya naa. Inu Ọbabinrin si dun lati darapọ mọọ pẹlu rẹ.
Asínijẹ́ tó dángájíá
Ni kọkọ, a gbọ pe Ọbabinrin jẹ ogbontagi ninu ka sin eeyan jẹ, sisọrọ bi ẹlomiran ati oniruuru ọna ibanisọrọ, gẹgẹ bi ọgbẹni Lacey, onimọ nipa itan "The Crown" loju opo Netflix ṣe sọọ.
Bakan naa ni wọn mọ ọ fun ṣiṣe bii adari orilẹede Russia tẹlẹ, Boris Yeltsin, ẹni to kọ iwe "The Wicked wit of Queen Elizabeth ll, Karen Dolby lo sọ bẹẹ.
Bakan lo ni o tun sin awọn oloṣelu atawọn atọkun ori ẹro amohunmaworan jẹ daadaa.
Ọgbẹni Lacey ṣapejuwe awada Ọbabinrin gẹgẹ eyi ti oun funrarẹ ri bii pe o n fi ara rẹ ṣe awada.
Gígé àkàrà òyìnbó pẹ̀lú ìdà
Ọpọlọpọ akara oyinbo ni Ọbabinrin ge nigba aye rẹ, lasiko kan, ida to wa fun ayẹyẹ lo fi bu akara oyinbo la. O ṣe eyi to yatọ si ilana kan saan to maa n tẹle ni gbogbo igba lọtẹ yii to si waye nibi ayẹyẹ ẹlẹyinju aanu kan ni Cornwall.
Nigba ti eeyan kan ran an leti pe iru ọbẹ bi ida yii lo wa nilẹ, Ọbabinrin ko ri eyi bi idiwọ rara, o ni "mo mọ pe o wa to si di ida naa mu ṣiṣin to tun ni "eleyi yatọ si ohun to ba igba mu".
Àwàdà kẹrí-kẹrì
Arabinrin Dolby kanlẹ fẹran itan Ọbabinrin nigba kan to ṣaadede pade awọn arinrinajo igbafẹ ara Amẹrika kan ti wọn jọ n rin lọninu ojo. Ọbabinrin ni tirẹ wa pẹlu ẹṣọ alaabo lẹgbẹ ile rẹ ni Balmoral.
Lai da a mọ pe oun lo wa ninu ẹwu ojo to yi mọra, arinrinajo igbafẹ naa bere lọwọ ẹni to wa ninu ẹwu ojo pe "nj o ti pade Ọbabinrin ri, Elizabeth si daa lohun pe "rara, amọ oun (o nawọ si ẹṣọ alaabo rẹ to wa lẹgbẹ rẹ) ti ri Ọbabinrin ri".
Lasiko mii to da rinrinajo lọ ibi kan to si n ra nkan funra rẹ ni Nortfolk, olutaja ibẹ sọ fun un pe: "o jọ Ọbabinrin gẹlẹ, afi bi ẹpa".
Ọbabinrin si daa lohun pe "o da ẹ loju gidi gan".
Ta lo le gbe ina woju ẹkun amọ...?
Lóòtọ́, ta ló leè gbé iná wojú ẹkùn ni wọ́n máa ń sọ ní ti àwọn Ọba aláṣẹ ekèjì Oòṣà.
Amọṣa, awada jẹ ọkan lara ọna ati mu ibẹru kuro lọkan awọn eeyan lasiko ti wọn ba wa layika rẹ, iyẹn Ọbabinrin Elizabeth.
Sir Anthony sọ pe "Ọbabinrin ni ipa lati da ara rẹ lara ya ati lati ri apa ile aye to pani lẹrin".
O ti pade ọpọlọpọ awọn adẹrinpoṣonu, to fi mọ Tommy Cooper, ẹni ti Arabinrin Dolby ranti pe o ti bere lọwọ Ọbabinrin ri pe njẹ o nifẹẹ bọọlu alafẹsẹgba.
Nigba to fesi pe oun ko fibẹẹ nifẹ sii, o wa sọ fun Ọbabinrin pe "to ba ri bẹẹ, njẹ ẹ lee fun mi ni awọn tikẹẹti rẹ ki n lọ fi wo aṣekagba FA Cup?".
Bakan naa ni wọn ni eto apanilẹrin ori Tẹlifisan, "The Kumars" jẹ ọkan lara eto ti Alayeluwa fẹran ju.
Fifun ara ẹni ni itura ati ifọkanbalẹ
Ọbabinrin maa n saba wo eto awọn ọtọkulu ilu nla nla. Ẹrin si jẹ pataki esi rẹ si iru awọn iṣlẹ to ba lee da eeyan laamu.
Ẹrin maa n jẹ ki eeyan turaka ninu ipaya. Bakan naa, o maa n fa awọn eeyan mọra. Bẹẹ si ni iroyin sọ pe ati Ọbabinrin ati Arẹmọ Philip ni wọn jọ jẹ alabapin ninu ki wọn jọ maa rẹrin papọ bayii.
Arabinrin Dolby ṣapejuwe bi Ọbabinrin kan ṣe rẹrin musẹ nibi eto itọwọbọwe kan lẹyin ti Olootu ilẹ Canada, Jean Chretien fi akọ pa ori gege rẹ de to si bura kete kete.
"O fẹran awọn nkan to da yatọ bakan bakan, bi nkan ba si waye bi ko ṣe yẹ ko waye, o ṣeeṣe ko gbaa si awada ju ko binu lọ", Sir Anthony sọ bẹẹ.
Ayaworan, Chris Young fi ẹrọ ayaworan rẹ gaani bi Ọbabinrin ṣe tu si ẹrin musẹ nigba ti awọn ọwọ kokoro oyin kan da eto abojuto awọn ologun kan ru ni Windsor Castle lọdun 2003.
"Mo moye pe asiko jijẹ ara ẹni ni", Ọgbẹni Young sọ.
"Ṣe lo n rẹrin musẹ bii ọmọdebinrin."
Ninu ọrọ ikini rẹ lasiko ọdun Kersimesi ti ọdun 1991, Ọbabinrin sọ ero ara rẹ nipa bi oun ṣe maa n ṣe awada.
"Ẹ ma jẹ ka mu aye le fun ara wa", o sọ bẹẹ.
"Ko si eeyan to lee dá gbọ́n."