You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èrè tíátà sọ mí dì Àjẹ, n kò mọ̀ pé wọ́n máa ń gba àjẹ́ - Oyiboyi
Gbajumọ oṣere tiata kan, Alhaja Serifat Ajileye, ẹniti ọpọ enia mọ si Oyiboyi ti sọrọ lori ipa to maa n ko bii ajẹ ninu ere tiata.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lori Ojopagogo TV to wa lori ayelujara ni Oyiboyi ti sisọ loju ọrọ naa.
Osere tiata naa ni oun kọ bi wọn ṣe n ṣe bi ajẹ ninu sinima lọwọ ọkọ oun, oloogbe Yekeen Ajileye, ẹni to kọ ere agbelewo ti akọle rẹ n jẹ Koto Aiye.
Serifat Ajileye wa ṣalaye pe ile iwe alakọbere ni oun ti n ṣe ere nitori o ti wa ninu ẹjẹ oun, ti oun ṣi ma n gbadura ṣi Ọlọrun pe iṣẹ ori itage lo wu oun, ki Ọlọrun to gba bẹẹ fun .
Serifat ni bo tilẹ jẹ wi pe oun ko pari ile iwe Girama, amọ ifẹ ti oun ni si ere ori itage lo mu oun de ọdọ Ologbe Ajileye, ẹni to pada fẹ sile gẹgẹ bi aya.
O ni awọn obi oun ko fẹ ki oun ṣere tiata, ọpọ igba si ni oun maa n yọ lọ se idanrawo ere nitori opopona kan naa ni ile awọn ati ti Ajileye wa.
Agba oṣere tiata naa ni inu oun dun nigba ti Yekini Ajileye kọ ẹnu ifẹ si oun, ti oun si gba fun.
Oyiboyi ni ti oun ko ba fẹ Ajileye, o ṣee ṣe ki oun ma ṣe ere tiata mọ.
"À ń n fi ìṣe àjẹ́ kọ́ àwọn ọmọ ni ọgbọ́n ni"
"Kii se awọn ajẹ lo pa ọkọ mi, Yekeen Ajileye, asiko rẹ lo to"
Alhaja Serifat Akinleye tẹsiwaju ninu ifọrọwerọ naa, to si sisọ loju rẹ pe bo tilẹ jẹ wi pe Yekini Ajileye ti ni iyawo kan ṣaaju oun, sibẹ iyale oun ko ba oun ja.
Serifat ni oun ko mọ pe wọn maa n gba ajẹ nitori bi akẹkọọ lẹnu ẹkọṣẹ ni oun bi wọn ti n ṣere bi ajẹ.
O tẹnumọ pe bii awọn ṣe n ṣe bi ajẹ ko sẹyin ẹkọ ti awọn fẹ kọ awọn ọdọ lati maa bọwọ fun awọn agbalagba.
O ni gẹgẹ bi oṣere, awọn ko bu awọn ajẹ, ṣugbọn awọn n fi ere kọ ọpọlọpọ ni ọgbọn nii,
Oyiboyi ni bo tilẹ jẹ wi pe ọkọ oun ti di ologbe, ti ahesọ ọrọ si n lọ pe awọn ajẹ ni wọn pa a, amọ o ni eyi ko ri bẹẹ nitori oun mọ pe asiko rẹ lo to.
Serifat ni Ajileye ti ṣe ọpọlọpọ ere to ni nnkan se pẹlu awọn ajẹ fun ọpọlọpọ ọdun, ti ko si ku amọ oun gbagbọ pe asiko to ku, ko sẹyin akọsilẹ rẹ pẹlu Ọlọrun.