You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Màbo tí ojú mí rí torí mó ṣúgbàá Tinubu kó ṣé sọ tán - Toyin Abraham pariwo síta
Gbajugbaja osere tiata, Toyin Abraham ti salaye ohun ti oju rẹ ri lasiko ìdibo aarẹ to waye losu to kọja, eyi to gbe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu wọle.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe lori Ayelujara ni Toyin Abraham ti ke gbajare bẹẹ.
O ni lati igba ti oun ti kede atilẹyin oun fun Tinubu, lawọn ọdọ kan lori ayelujara ti bẹrẹ si gbe ogun ti oun, ti wọn si n pe fun isubu oun yika agbaye.
O ni ibi tí awọn eeyan gbiyanju to lori ìṣubu oun, o ni wọn kọ lẹta si awọn ileeṣẹ ti oun ba dowopọ pe ki wọn gba isẹ lọwọ oun.
"Lori opo kan lori Ayelujara, mo ri pe awọn ko ni wo Sinima mi mọ"
"Lori opo kan lori Ayelujara, mo ri pe awọn ko ni wo Sinima mi mọ, koda wọn kọwe si Netflix pe ki wọn yọ gbogbo sinima mi danu.
"Awada ni mo pe nitori mo ṣe atilẹyin fun Tinubu.
Ń ko se ohun to lodi sofin, n ko jale, n nko pa eeyan, ko si si ẹni to salabapade mi, to ma ni mo ṣe ika fún un rí."
"Torí pe ọmọ jẹ akíkanjú ni, wọn ni awọn yoo ba aye mi jẹ "
Toyin Abraham tẹsiwaju pe ọpọ awọn oṣere tiata ni ko le jade síta lati se ẹtọ wọn fun Orilẹede Naijiria nítorí wọn bẹru ohun tí awọn eeyan ma sọ jade lori ìpinnu wọn
"Pupọ wa ni a ko le sori pe nnkan bayi ni a fẹ, n ṣe wọn fẹ gba oúnjẹ lẹnu wa nitori a kọ lati tẹle oludije wọn.
"Aye wa lẹyin Ayelujara, mo sọ fun wọn, nko kí ṣe ọmọde ninu isẹ yìí."
"Ọrọ naa dabi pe emi ni mo gbe apoti ibo ni"
"Mo dupẹ lọwọ awọn eeyan to duro ti mi"
Oṣere naa wa dupẹ lọwọ awọn eeyan to duro tí lasiko ti ọrọ naa bẹrẹ.
O ni asiko naa da bí pe oun gan lo gbe apoti ibo lati dupo aarẹ.
Toyin ni pẹlu igbiyanju awọn eeyan yii, gbogbo idokowo oun lo siwa ni kampe.
"Mo ní lati jẹ ki awọn eniyan mọ nípa nnkan ti awọn eeyan kan le se tí ẹ ba se atilẹyin fun oludije wọn."