You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìrírí aráàlú rèé bí CBN ṣe ní kí wọ́n máa ná Naira àtijọ́
Awọn eniyan ti bẹrẹ si ni sọ iriri wọn lẹyin ti ileeṣẹ ifowopamọsi to gajulọ lorilẹede Naijiria, CBN, ti kede ni alẹ ọjọ Aje pe ki banki maa fun awọn eniyan ni owo atijọ to ba wa ni ikawọ wọn.
Lara awọn to ba awọn akọroyin sọrọ ni awọn banki ti n fi owo atijọ naa sita amọ owo ko i tii to fun awọn eniyan.
Bi o tilẹ jẹ pe ikede CBN naa yẹ ko wa ojutu si ọrọ aisi owo amọ iwadii fihan pe o ṣeeṣe ki aisi owo tabi airi owo gba naa le ma wa si opin laipẹ.
Iwadii fihan pe ẹgbẹrun marun un naira, 5000 naira ati ẹgbẹrun marun un naira, 10,000 naira ni awọn banki n fun awọn araalu nipinlẹ Eko, Abuja, Ogun ati Kwara.
Awọn Banki ní Eko fi owo atijọ si ATM
Aisi owo naa ti mu ki ileeṣẹ ifowopamọsi Wema Bank ni ilupeju fun awọn eniyan to n gba owo ni nidi ATM ni 10, 000 naira to ba jẹ banki Wema ni wọn lọ.
Amọ 4000 naira pere ni wọn n fun awọn to ba wa lati banki miran lati wa gba owo ni ori ATM wọn.
Bakan naa ni awọn eniyan to sọ iriri wọn ni Banki naa n san owo atijọ fun wọn.
Awọn miran to sọ iriri wọn ni awọn banki miran nipinlẹ Eko ni Banki Access Bank ni agbegbe CMD Ikosi road sọ fun awọn eniyan wọn pe ẹnikẹni to ba fẹ fi owo sinu apo iṣuna rẹ to si jẹ owo atijọ gbọdọ gba code lati oju opo ayelujara CBN, ki wọn to le fi owo atijọ naa si banki wọn.
Nina owo Naira atijọ
Iwadii tun fihan pe awọn eniyan ni awọn ọja ati ojukọ itaja to fi mọ awọn awakọ ti bẹrẹ si ni gba owo atijọ naa.
Amọ awọn to ba ileeṣẹ iroyin Punch sọrọ ni awọn ọlọja ni agbegbe Oshodi nipinlẹ Eko ti bẹrẹ si ni gba owo atijọ naa pada.
Bakan naa ni wọn fikun pe awọn awakọ oju popo miran to fẹ kọ owo atijọ naa n pada gbaa lẹyin ti awọn ero inu ọkọ ba yari pe awọn ko ni owo miran yatọ si owo atijọ.
Awọn to ba awọn oniroyin sọrọ naa ni awọn ojuko POS naa n fun awọn eniyan ni owo atijọ,ti awọn naa si n gba lọwọ awọn araalu.
Nibayii, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC kede gbedeke ọjọ meje ti wọn fun ijọba lati wa ọna abayọ si aisi owo naa.