You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí mẹ́jọ lórí ìjínigbé awọn akẹ́kọ̀ọ́ nípìnlẹ̀ Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti sọ pe ọwọ oun ti tẹ afurasi mẹjọ to lọwọ ninu ijinigbe awọn ọmọ ileewe Apostolic Faith Montessori School Emure Ekiti.
Awọn eniyan yii kan naa ni wọn lo gbe ati alaga egbe oselu All Progressive Congress (APC), Hon Paul Omotosho ni ọdun to koja.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji, ni ọwọ tẹ àwọn afurasi naa.
Nigba to n fi oju awọn afurasi naa han, kọmisanna ọlopaa ni nipinlẹ Ekiti, Adeniran Akinwale, sọ pe ibọn pa afurasi kan.
Ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kinni, ni wọn jì awọn akekọọ naa lasiko ti wọn n pada sile.
Awọn ti wọn jigbe yii, akẹkọọ marun un, olukọ obinrin meji ati awakọ ni wọn ko si ọwọ awọn ajinigbe nigba ti wọn n dari ile ẹkọ pada nirọlẹ
Bawo ni ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi naa?
Kọmisanna ọlọpaa sọ pe nibi ti awọn afurasi naa ti fẹ ẹ jí awọn ọmọ ilẹ okeere kan gbe ninu oko ti wọn ti n ṣe wàrà, niluu Ikun-Ekiti, lọwọ ti tẹ Abubakar Aliyu.
Oun lo wa a fimu finlẹ ibi ti awọn ọmọ ilẹ okeere naa wa.
Lẹyin ti ọwọ tẹ Aliyu, ni olori ikọ ajinigbe naa, Sumo Karami, ran fijilante meji, Saliu Ibrahim ati Umaru Saliu, lati gba beeli Aliyu ni ahamọ ọlọpaa.
Awọn ọlọpaa to wa fun iṣẹlẹ pajawiri, RRS, mu awọn mejeeji.
Lẹyin naa ni wọn mu àwọn ọlọpaa lọ si ilu Oro-Ago, nipinlẹ Kwara.
Nibẹ ni ọwọ ti tẹ Mohammed Bashiru, olori Miyetti Allah vigilante to wa nibẹ.
Oun lo si jẹwọ pe Sumo Karami, to jẹ ibatan rẹ, ni olori awọn ikọ to ji awọn akẹkọọ ati olukọ wọn gbe niluu Emure-Ekiti.
Lara awọn nnkan ti wọn kọkọ gba lọwọ wọn ni foonu ti wọn fi beere fun owo itusilẹ awọn akekọọ ati olukọ wọn.
Ọwọ awọn ọlọpaa tun pada tẹ ọmọ ikọ naa meji, Yahaya Jubril and Usman Garba ninu aginju kan niluu Owo, ipinlẹ Ondo.
Afurasi miran ti ọwọ tun tẹ niluu Ibadan, Kenneth Igwu, lọjọ kẹrinla, oṣu Keji, lo ṣe atọna bi awọn ọlọpaa RRS ṣe de ibuba awọn ajinigbe naa ninu igbo nla kan to wa laarin Ise-Ekiti/Emure-Ekiti.
Ṣugbọn ṣa, ẹnikan pere ni ọwọ tẹ, nitori pe awọn to ku raaye gba inu igbo salọ.
Báyìí láwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ekiti ṣe padà gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé
Iroyin to wa lọwọ bayii sọ pe awọn ọmọ ileẹkọ the Apostolic Faith Apostolic Montessori School Emure Ekiti ti won jigbe gba itusilẹ lẹyin ọsẹ kan.
Alex Abutu to jẹ alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti sọ pe gbogo awọn to wa ni akata ajinigbe lo ti gba itusilẹ bayii. Amọ o sọ pe dirẹba ọkọ naa ko dari pada laaye. O ni awọn fura si pe awọn ajinigbe naa ti pa a.
Botilẹ jẹ pe ko sọrọ boya wọn koju awọn ajinigbe naa ni ki wọn to tu awọn akẹkọọ yi silẹ tabi wọn san owo idoola ẹmi, awọn ẹbi sọ pe awọn san owo.