You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọmọ oṣù kan jáde láyé lẹ́yìn tí wọ́n dábẹ́ fún un
Ijọba orilẹede Gambia ti bẹrẹ iwadii lori iku ọmọ oṣu kan to jade laye lẹyin ti wọn da abẹ fun un.
Abule Wellingara ni iṣẹlẹ naa ti waye, o si ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ lorilẹede ọhun.
Ninu atẹjade kan, ọlọpaa ni niṣe ni ẹjẹ bẹrẹ si n da loju ara ọmọde jojolo naa lẹyin iṣelẹ ọhun.
Iwadii ti wọn ṣe nile iwosan fi han pe lootọ ni wọn fi abẹ ṣisẹ fun ọmọ ọhun.
Wọn ti bẹrẹ si n ṣe ayẹwo oku ọmọ naa bayii lati mọ ni patọ boya abẹ ti wọn da fun lo ṣokunfa iku rẹ.
O kere tan, obinrin meji lo ti wa ninu atimọle ọlọpaa bayii lori iṣẹlẹ naa.
Ẹwẹ, awọn ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, wọn si ti n bere fun idajọ ododo lori rẹ.
Ọkan lara ẹgbẹ naa, Women In Leadership and Liberation (WILL), ti fẹsun kan ijọba pe o kuna lati daabo bo awọn ọmọde orilẹede naa.
Ẹgbẹ ọhun sọ pe "aṣa kii ṣe awawi fun iṣẹlẹ yii, iwa ipa gbaa ni eyii jẹ, ko ju bẹẹ lọ."
Ẹgbẹ naa tun rọ ijọba lati ṣe iwadii to peye lori iṣẹlẹ naa ko si fi imu gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ danrin.
Oludasilẹ ajọ naa, Fatou Baldeh, sọ fun BBC pe kii ṣe igba akọkọ ree ti wọn yoo da babẹ fun ọmọde ni Gambia, iwa naa si ti n peleke siwaju si.
O ni "awọn obi ro pe ti wọn ba tete dabẹ fun ọmọ wọn ni kekere jojolo, oju egbo naa yoo tete jina, wọn tun ro pe wọn le tete ṣe nigba ti awọn ọmọ naa ba wa ni kekere ki awọn eeyan ma le tete mọ."
Ọmọ ile igbimọ aṣofin kan lagbegbe ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, Abdoulie Ceesay ti pe fun iwadii ni kikun lati le daabo bo ọjọ ọla awọn ọmọde nibẹ.
Iye eeyan ti wọn n dabẹ fun ni Gambia
Atẹjade kan lati ọdọ ajọ UNICEF sọ pe ọmọdebinrin mẹta ninu mẹrin ni wọn n da abẹ fun ni Gambia ki wọn to pe ọmọ ọdun mẹfa.
Ajọ UN tun ni ida 76% obinrin laarin ọdun marundinlogun si ọdun mọkandinlaadọta ni wọn dabẹ fun ni Gambia.
Bo tilẹ jẹ pe lati ọdun 2015 ni wọn ti fofin de didabẹ fun obinrin lorilẹede naa eeyan meji pere lo tii jẹjọ lati ọdun ọhun.
Lọdun to kọja, awọn kan gbe igbesẹ lati fofin de iwa naa amọ ile igbimọ aṣofin ilẹ ọhun ko jẹ ko ṣeeṣe.