Comfort Emmanson gba ìtúsílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ile ẹjọ majistreeti kan lagbegbe Ikeja, niluu Eko ti tu Comfort Emmanson silẹ ni ahamọ ọgba ẹwọn lẹyin to da wahala silẹ to si gba oju ọkan lara oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air niluu Eko.

Adajọ Olanrewaju Salami tu ọdọbinrin naa silẹ lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ko nifẹ si ati tẹsiwaju ninu ṣiṣẹ ẹjọ ẹsun marun un ọtọtọ ti wọn fi kan an mọ.

Ẹwẹ, ṣaaju igbesẹ yii ni minisita fun ọrọ irinkerinde ọkọ ofurufu ni Naijiria, Festus Keyamo, (SAN), ti kọkọ kede loju opo X rẹ pe ki wọn fi silẹ.

Keyamo sọ pe ọpọ araalu lo ba afurasi naa bẹbẹ, a ti pe o ti mọ ẹjọ rẹ lẹbi lawọn ṣe yọ okun ẹjọ lọrun rẹ.

O fi kun pe ileeṣẹ ọkọ ofurufu Ibom Air naa ti gba lati jawọ kuro ninu ẹjọ ati ẹsun ti wọn fi kan afurasi ọhun.

Ọjọ Aje ọsẹ yii ni Emmanson foju bale ẹjọ, bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ gba beeli rẹ amọ wọn fi si ahamọ ọgba ẹwọn latari pe ko ri ohun to nilo fun beeli ọhun.

Kí ni ìdí tí Kwam 1 kò ṣe jẹ́jọ́ nígbà tí Comfort Emmanson dèrò àtìmọ́lé lórí ìwà wọn ní pápákọ̀ òfúrufú Eko?

Ajọ to n ri si irinkerindo ọkọ ofurufu ni Naijiria, NCAA, ti sọrọ lori eredi ti Kwam 1 ko ṣe foju bale ẹjọ lẹyin iwa to wu si ileeṣẹ baalu ValueJet amọ ti Arabinrin Comfort Emmanson jẹjọ lẹyin ti oun naa wu iwa to fara jọ iru ohun ti Kwam 1 ṣe si Ibom Air.

Agbẹnusọ ajọ Nigeria Civil Aviation Authority, NCAA, Mike Achimugu, sọ fun ileeṣẹ iroyin Channels pe K1 De Ultimate ko dero ile ẹjọ latari pe ileeṣẹ ValueJet ko pe ẹjọ tako o.

O ni "ileeṣẹ ti Kwam 1 ṣẹ si ko lo ẹtọ rẹ lati gbe e lọ sile ẹjọ.

"Fun idi eyii, ajọ NCAA kọ iwe ẹbẹ si awọn to yẹ lati ba arinrinajo naa jẹjọ, lẹyin naa ni a gba ẹgbẹ awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu lamọran pe ki wọn fofin de Wasiu lati ma le fo."

Amọ nigba to n sọrọ nipa onibara Ibom Air nibi ti arinrinajo naa ti lu oṣiṣẹ ileeṣẹ ọhun, o ṣalaye pe ileeṣẹ ọkọ ofurufu akero naa funra rẹ lo gba ile ẹjọ lọ.

O ni "boya nitori wọn lu onibara wọn lo jẹ ki ileeṣẹ naa tete gbe ọrọ ọhun lọ silẹ ẹjọ lai fi akoko ṣofo, nitori naa, ajọ NCAA ko lọwọ ninu bi ọrọ naa ṣe dele ẹjọ."

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kan naa ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn gbe arinrinajo naa, Emmanson Comfort lọ sile ẹjọ ti ile ẹjọ si fi si ahamọ ọgba ẹwọn.

Achimugu ṣalaye siwaju si pe awọn iṣẹlẹ ẹnu lọlọ yii n ṣafihan pe awọn ileeṣe ọkọ ofurufun ni Naijiira – to fin mọ ajọ FAAN, AVSEC, atawọn arinrinajo funra wọn - ni ọpọ iṣẹ lati ṣe."

O fi kun pe ko si ibikibi ni gbogbo agbaye ti wọn ti n faye gba iwa tani yoo mu mi awọn papakọ ofurufu.

Gẹgẹ bo ṣe, awọn ofin atawọn ilana papakọ ofurufu wa fun abo awọn arinrinajo funra wọn, ko si si ojuṣaju kankan ninu rẹ.

Achimugu fi kun pe gbogbo awọn arinrinajo lọ gbọdọ gbọrọ si awọn oṣiṣe baalu lẹnu ni papakọ ofurufu.

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn ọlọkọ ofurufu ni Naijiria, AON, ti fofin de ọdọbinrin naa pe ko ni le wọ ọkọ ofurufu ni Naijiri mọ titi aye.

Eyii kan ọkọ ofuru labẹle ni Naijiria atawọn ọkọ ofurufu to n lọ soke okun lori ẹsun pe o gba oju oṣiṣẹ Ibom Air.

Iléeṣẹ́ bàlúù Ibom Air ṣàláyé ohun tó ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú obìnrin tó fà wàhálà ni pápákọ̀ òfurufú lọ́jọ́ Àìkú

Ileeṣẹ baaluu Ibom Air ti ṣalaye ohun to waye laaarin oṣiṣẹ baaluu naa ati Arabinrin Comfort Emmanson, obinrin to si iya fun oṣiṣẹ baaluu.

Ibom Air ni kete ti awọn gbera kuro ni Uyo ni oṣiṣẹ baaluu kan si pe ko tẹle ofin ati ilana to wa ninu baaluu ti o si kọja jalẹ titi Ọga agba to n lewaju baaluu to kede.

Ileeṣẹ naa ni ọrọ yii fa ariyanjiyan laaarin Arabinrin Emmason ati oṣiṣẹ baaluu ṣugbọn wọn pada petu si ọrọ naa, ti wọn si gbera kuro ni Uyo

Ibom Air ni kete ti baaluu balẹ si ilu Eko, arabinrin Emmanson duro fun gbogbo ero lati sọkalẹ, to si kọlu oṣiṣẹ baaluu to ni ko tẹle ofin ati ilana baaluu.

"Emmanson lọ ba awọn oṣiṣẹ baaluu, to si fa irun rẹ, yọ giigi rẹ, fọ mọlẹ, to si yọ bata lati fi lu oṣiṣẹ baaluu naa.

"O ko ọpọ ifọti fun oṣiṣẹ baaluu naa, koda eeyan to igbiyanju lati da si ọrọ naa tun jẹ igbaju. Emmanson lọ gbe ohun to pa ina lati fi kọlu oṣiṣẹ baaluu."

IbomAir ni ọga agba baaluu naa ke pe awọn ẹsọ alabo, ti oṣiṣẹ baaluu si mu Emmanson balẹ ko duro ki oṣiṣẹ alabo de.

"Gẹgẹ bii o ṣe wa ninu fidio lori ayelujara, arabinrin Emmanson tun kọlu awọn ẹsẹ alabo, o tun fọ oṣiṣẹ alabo ni ifọti ."

IbomAir ni kete ti wọn gbe Emmanson kuro ninu baaluu ni ajọ FAAN fa le ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ fun iwadii.

"Arabinrin Emmanson, a ti fi ofin de arabinrin yii, ko ni ni anfani lati gun baaluu wa mọ."

Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ KWAM1, arìnrìnàjò míràn tún dá wàhálà sílẹ̀ ní pápákọ̀ òfurufú kan ní Nàìjíríà

Arin irinajo kan to fẹ gun baalu Ibom Air lati Uyo lọ si ilu Eko da wahala rẹpẹtẹ silẹ ni paapa ofurufu Muritala Muhammed lọjọ Aiku, to si gbe ija kọlu awọn oṣiṣẹ baalu naa atawọn oṣiṣẹ paapakọ ofurufu.

Fọnran kan ti BBC News Yoruba ri loju opo ayelujara kaakiri, paapaa ti @OHOgunbiyi fihan bi obinrin kan ṣe n ba awọn oṣiṣẹ baluu Ibom air ati papakọ ofurufu naa fa wahala, koda pe

"Ọjọ mii, wahala mii ni paapa ofurufu laaarin arin irinajo to wọ @ibomairlines ati AVSEC ni paapa to wa ni Eko. Arin irinajo naa lo gbera lati Uyo wa si ilu Eko. O tun ti n sẹlẹ"

Bẹẹ ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni wahala kan bẹ silẹ laaarin Gbajugbaja olorin Fuji ati awọn oṣiṣẹ paapa ofurufu niluu Abuja.

Ninu fọnran miran ti a tun ri lori ayelujara, ọdọmọbirin to wọ iyaja pẹlu awọn oṣiṣẹ paapa ofurufu ni o wọ aṣọ funfun pẹlu sokoto dudu, to si n ju ọpọ nnkan mọ awọn oṣiṣẹ bi wọn se n gbiyanju lati pẹtu si lọkan.

Fọnran ọhun ka obinrin naa bi o ṣe n kọlu awọn oṣiṣẹ paapa ofurufu, ti awọn to si wa nib ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ pe obinrin naa gba oṣiṣẹ paapa ofurufu naa leti ni igba meji ọtọọtọ.

Wahala naa pọ, to jẹ awọn ọlọpaa paapa ofurufu lo wa bu omi pa ina laaarin igun mejeeji.

Ki gan an lo fa ija yii?

Nigba to n fesi si iṣẹlẹ ọhun, agbẹnusọ fun Ajọ the Nigeria Civil Aviation Authority, NCAA, Micheal Achimugu ni gbogbo rogbodiyan eyi waye nitori aigbọran arin irinajo lati tẹle ofin ati ilana wiwọ baalu.

O ni " Nigba ti awọn oṣiṣẹ baalu b ani ki ẹ pa foonu yin ṣaaju ki baalu to gbera, ẹ gbọran . Ko ye mi idi ti nnkan kekere ma fa irufẹ wahala bayii.

"Eyi ni lati ye awọn arin irinajo pe wọn ni ojuse wọn lati ṣe, ki ṣe ẹtọ."

Ki lo sẹlẹ saaju?

Ajọ to n ṣe amojuto awọn papakọ ọkọ ofurufu ni Naijiria, Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN), fẹsun kan gbajugbaja akọrin Fuji, Wasiu Ayinde, ti ọpọ eeyan tun mọ si KWAM 1, pe o da ọti si awọn oṣiṣẹ ọkọ baalu lara ni papakọ Nnamdi Azikiwe Airport niluu Abuja, lọjọ Iṣẹgun.

Ajọ FAAN sọ ninu atẹjade kan ti oludari ẹka ibaraalu sọrọ ati ẹtọ araalu, Arabinrin Obiageli Orah, fi sita pe ihuwasi Ayinde tako ilana irinajo ofurufu.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni iwadii ti awọn kọkọ ṣe, ṣafihan rẹ pe Wasiu Ayinde n rinrinajo lati ilu Abuja l si Eko, pẹlu baalu ileeṣẹ ValueJet, nibi to ti gbiyanju lati gbe nnkan olomi ti ko lo 'lorukọ' wọ inu baalu, tako gbogbo ikilọ ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo fun un, to fi mọ ti ọga awakọ baalu.

"Gẹgẹ bi ofin irinna, nnkan olomi to ba ti pọ ju 100ml lọ, ko le wọ inu baalu, ayaafi to ba jẹ pe iru nnkan bẹ wa fun ilera, ti ẹni to ni i si ṣafihan rẹ bo ṣe yẹ."

Gbogbo alaye yii ni FAAN sọ pe wọn ṣe fun KWAM 1, ṣugbọn to kọ lati tẹle e.