'Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí mo ṣe ní ọdún mẹ́fà sẹ́yìn lórí ìgbéyàwó mi ni ẹ̀ ń gbé kiri'

Gbajugbaja oṣere tiata, Bolanle Ninalowo ti fọnu sita lori ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ BBC Yoruba ti awọn ẹka iroyin mii sare n gbe jade nibi to n ti n sọrọ nipa gbogbo kudiẹkudiẹ to waye ninu igbeyawo rẹ.

Ọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja ni Ninalowo kede fun araye pe oun ati iyawo rẹ, Bunmi Ninalowo ti tu igbeyawo wọn ka fun keji.

Kete ti Ninalowo kede ituka ni ọpọlọpọ fọnran gba ori ayelujara ọkan nibi to n ti n sọrọ bi o ṣe fi ọbẹ ẹyin jẹ iyawo rẹ niṣu, eyi to fa ti ituka fi waye laarin wọn ni igba akọkọ, ki awọn mejeeji to wa pada gẹgẹ bi tọkọ taya.

O bu ẹnu atẹ lu awọn akọroyin ti wọn n lo fọnran naa, to si ni oun ko ni alaye kankan lati ṣe fun ẹnikẹni lori idi to fi gbe igbesẹ naa.

“N ko ni alaye ti mo fẹ ṣe fun ẹnikẹni fun igbesẹ ti mo gbe laye mi.

“Gbogbo ifọrọwerọ to n gba ori ayelujara lo jẹ eyi ti mo ti ṣe ni ọdun mẹfa sẹyin ki n to yanju aawọ igbeyawo mi nigba naa, ko to wa tuka bayii.

“Emi mo n ṣe ajọyọ, ẹyin ni ara n ta, Ọlọrun to ran mi lọwọ yoo ran yin lọwọ.”

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Lọjọ Ẹti, ọsẹ to kọja ni Bolanle Ninalowo kede pe oun ati iyawo rẹ, Bunmi Ninalowo ti tu igbeyawo wọn ka.

O gbe ọrọ yii sori opo ayelujara rẹ, to si ni oun ti ṣetan lati gba pe opin ti de ba irinajo oun ati iyawo oun bayii.

Bakan naa lo ni igbesẹ yii yoo fi aye silẹ fun ọjọ iwaju rere.

"Ni bayii, Mo ti gba pe opin ti de ba irinajo yii. Igbesẹ yii ni lati fi aye silẹ fun ọjọ ọla rere.

"Igbeṣe yii ba awọn ọmọ mi lọkan jẹ ṣugbọn ti a nilo fun ọjọ ọla rere."

Ki ni Bolanle Ninalowo sọ ninu ifọrẹwerọ to ṣe pẹlu BBC?

Ọdun 2018 ni Bolanle Ninalowo ṣe ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ BBC, ro si ṣalaye ohun to waye laarin oun ati iyawo rẹ Bunmi, ati bi irinajo ifẹ wọn ṣe bẹrẹ.

O ni oṣu mẹfa ti wọn bẹrẹ ere ifẹ ni iyawo oun loyun, ti oun si gbe lọ si ilu Oyinbo.

O ṣalaye gbogbo ohun to lakọja pẹlu iyawo rẹ ati idi to pinnu lati tu igbeyawo naa ka fun igba akọkọ

Ọrọ pọ lẹnu Bolanle Ninalowo, ẹ wo fọnran yii.