Ẹ gbé òkú àwọn méjì tẹ́ẹ pa nílé Sunday Igboho jáde tàbí ká pàdé nílé ẹjọ́! - Agbẹjọ́rò Sunday Igboho sí DSS

Oríṣun àwòrán, Instagram
Àgbà agbẹjọ́rò Yomi Aliyu tó jẹ́ agbẹjọ́rò Olóyè Sunday Adeyemo tó ń pè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Sunday Igboho ti pe àjọ iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ilẹ̀ Nàìjíríà ìyẹn DSS níja.
Ohun tí Yomi Aliyu ń bèèrè fún lọ́wọ́ DSS ni pé kí wọ́n gbé òkú àwọn ènìyàn méjì tí wọ́n pa ní ilé Sunday Igboho tó wà ní agbègbè Soka, ìlú Ibadan ní ọjọ́ Kìíní oṣù Keje ọdún 2021 fún àwọn tàbí kí àwọn pàdé nílé ẹjọ́.
Aliyu nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Kẹjọ ọdún 2023 bu ẹnu àtẹ́ lu bí àwọn òṣìṣẹ́ DSS náà ṣe yawọ ilé Sunday Igboho tí wọ́n sì pa ènìyàn méjì sí ilé rẹ̀, tí wọ́n sì tún fi àwọn méjìlá mìíràn sí àhámọ́ nítorí bí Sunday Igboho ṣe ń tako ìwà Fulani darandaran tó ń pa àwọn ènìyàn ní ìlú Ibarapa, ìjọba ìbílẹ̀ Igangan, ìpínlẹ̀ Oyo.
Ó ní òkú Olalekan Adisa àti Imam Yekinni Olatubosun Abdulfatah tí àwọn DSS náà yìbọn pa lásìkò ìkọlù ọ̀hún ni àwọn DSS kò ì tíì gbé okú wọn kalẹ̀ débi tí àwọn ẹbí wọn fi máa ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn tó tọ́ fún wọn.
Nínú ẹjọ́ tó pè síwájú ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Oyo tó wà ní Ibadan láti fi bèèrè fún òkú àwọn olóògbé náà, Aliyu ní àwọn opó àtàwọn ọmọ olọògbé Olalekan Adisa ti pé ẹjọ́ láti bèèrè fún òkú bàbá wọn.
Ó ní DSS ti fẹ́ gbé òkú náà fún ilé ẹ̀kọ́ fásitì láti fi ṣe àyẹ̀wò tó sì ní àwọn ẹbí rẹ̀ ń bèèrè fún N254b gẹ́gẹ́ bí owó gbà màbínú.
Bákan náà ló ní àwọn ẹbí àti ọmọ Abdulfatahi náà ti pe ẹjọ́ ti wọn.
Ó fi kun pé bí àwọn ṣe ń retí kí ìjọba yan agbẹjọ́rò àgbà tuntun fún orílẹ̀ èdè yìí, ó ní láti ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kẹfa ọdún 2023 ti àwọn ẹbí ti àwọn àwọn olóògbé ti pe ẹjọ́ tako DSS, DSS kọ̀ láti fèsì sí lẹ́tà wọn.
Ìyàwó olóògbé Adisa, Abisola nínú ẹjọ́ tó pè pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ rọ ilé ẹjọ́ láti pa ní dandan fún DSS láti gbé òkú ọkọ̀ òun kalẹ̀ fún àyẹ̀wò, kí wọ́n sì tún san owó ìtanràn fún ẹbí àwọn.
Aliyu tún fẹ̀sùn kan nínú ẹjọ́ tó pè pé ogun ènìyàn ni àwọn DSS kọ ní ilé Sunday Igboho, tí wọ́n sì fún àwọn ọmọdé àtàwọn obìnrin tó wà níbẹ̀ í wọ́n kọ lọ sí Akure ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírà láti fi wọ ọkọ̀ padà sí Ibadan.
Ó fi kun pé ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu pé DSS kò fi ológbò tí wọ́n yìbọn lù tí wọ́n rò pé Sunday Igboho ni léde fún gbogbo ènìyàn láti rí tàbí kí wọ́n gbe wá sílé ẹjọ́.















