Nítorí owó, àwọn alálàájì láti Nàìjíríà yarí fún àjọ Hajj ní Mecca

Awọn alalaaji lati ilu Abuja lọ si Meka ni wọn ti fi ẹhonu han bayii si ajọ National Hajj Commission of Naigeria (NAHCON), to n ri si irinajo lọ si Saudi Arabia.

Wọn ni wọn ṣe magomago lori owo to yẹ ki wọn fun awọn fun lati ra nnkan ni Meka.

Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn afẹhonuhan naa ṣe ṣalaye fun BBC lorii foonu, o ni loootọ lawọn ti de Saudi lati ṣiṣẹ Haji.

Arinrinajo naa torukọ ẹ jẹ Hajjatin, sọ pe ẹẹdẹgbẹta dọla (500 dollars) ni ajọ NAHCON sọ pe awọn yoo fun arinrinajo kọọkan.

O ni nigba tawọn fẹẹ gbera ni Naijiria, wọn fun awọn ni igba dọla (200 dollars), wọn si lawọn yoo gba eyi to ku tawọn ba de Saudi.

‘’Nigba ti a de Saudi ti a beere owo wa to ku, wọn sọ fun wa pe igba dọla yẹn naa la maa gba.

‘’Wọn ni iyatọ ti de ba iye ti wọn n ṣe dọla nigba ta a fẹẹ maa bọ ati lasiko yii, nitori naa, awọn ko le fun wa ju bẹẹ lọ.

‘’Ki i ṣe adehun ti wọn ba wa ṣe ree, awọn kan ni wọn ge owo wa sẹyin’’

Bẹẹ ni arinrin ajo naa wi.

Àwọn tí wọ́n ti f’owó ṣe ẹyín Meka pẹ̀lu ìrètí pé wọ́n máa rí owó NAHCON gbà ti ń mọ̀ ọ́ lára báyìí

Ọkunrin kan naa ṣalaye pe ki i ṣe awọn arinrinajo lati Abuja nikan ni ọrọ yii kan.

O ni o kan awọn ipinlẹ mi-in lati Naijiria naa.

O ṣalaye pe wahala owo ti wọn ge ku yii ti n pa awọn obinrin Naijiria lara pupọ bayii.

‘’Idi ni pe pupọ ninu wọn lo ti fi owo to wa lọwọ wọn tẹlẹ ṣe eyin Meka.

‘’O si kere tan, ọgọrun-un dọla (100 dollars) ni eyin Meka kan.

‘’Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, wahala gidi lawọn obinrin n koju, nitori wọn ti fi owo ọwọ wọn ra nnkan tan, wọn n reti owo NAHCON ni.

‘’Ko fi bẹẹ si iṣoro fawọn ọkunrin ni tiwọn.’’

Bayii ni arinrinajo naa wi.

Àlàyé NAHCON lórí ọ̀rọ̀ yìí

Ikọ iroyin BBC kan si Muhammad Lawan Aliyu, agbẹnusọ fun ajọ NAHCON l’Abuja.

Aliyu ṣalaye pe ohun to ṣẹlẹ yii ki i ṣe ẹjọ NAHCON.

O ni,’’Ajọ to n ri sin irinajo mimọ ni Naijiria sọ pe oun yoo fun arinrinajo kọọkan ni 500 dollars. Nigba yẹn si ree, 1,250 ni wọn n ṣẹ dọla kan si Naira.

Ṣugbọn nigba ti a de banki, 1,530 la ba dọla kan."

" Eyi lo fa a ti a fi yi owo ti a ya sọtọ fun ounjẹ wọn gan-an pada, nitori bi ẹyin naa ba gbe iṣiro le e bayii, ẹ maa ri i pe dipoo 500 dollars, 415 lo wa fun arinrinajo kan."

Agbẹnusọ NAHCON ṣalaye pe ajọ naa ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ yii fawọn arinrinajo, awọn si ti ṣeleri lati gbe igbesẹ to yẹ.