You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí tí mi o fi gbìyànjú láti sọ Oluremi Tinubu ìyàwó mi di mùsùlùmí - Ààrẹ Tinubu
Aarẹ Bola Tinubu ti ṣalaye idi ti ko fi gbiyanju lati sọ iyawo rẹ, Sẹnetọ Oluremi Tinubu, di musulumi.
Tinubu ni oun gbagbọ ninu ifẹ ati ominira lati ṣe ẹsin to ba wu ẹnikẹni laye.
Nigba to n sọrọ laipẹ yii nibi eto isinku mama Nana Lydia Yilwatda, iya Ọjọgbọn Nentawe Yilwada, alaga ẹgbẹ oṣelu APC niluu Jos, Aarẹ Tinubu sọ pe ẹsin ọtọọtọ toun ati iyawo oun n ṣe ko fa ija ri laarin awọn mejeeji.
Aarẹ Naijiria ni wọn bi oun sinu ẹsin Islam ni, lati kekere loun si ti n tẹlẹ ilana ẹsin musulumi.
Amọ, Tinubu ni oun gbagbọ ninu ominira lati ṣe ẹsin to ba wu onikaluku.
Tinubu ni Ọlọrun kan naa loun ati iyawo oun jọ n sin, Ọlọrun yii kan naa si lawọn yoo jabọ fun.
Aarẹ ni nnkan to ṣe pataki julọ ni iwa eeyan ati ifẹ ti eeyan ba ni fun ẹlomiran.
Aarẹ Tinubu wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa gbe ni alaafia pẹlu ara wọn.
''Ko yẹ ki enikẹni korira ẹlomiran, ifẹ lo yẹ ki a maa gbiyanju lati ni fun gbogbo eeyan.
Ko si ẹnikẹni to le yi nnkan ti Ọlọrun ba ti kọ pada, ileri Ọlọrun ati nnkan to n ṣe lo ṣe pataki.
Mo jogun ba ẹsin Islam ninu ẹbi wa ni, mi o si yi i pada.
Ṣugbọn pasitọ ni iyawo mi, o si maa n gbadura fun mi, ko si ija kankan nibẹ,'' Tinubu lo sọ bẹẹ.