A ò lọ́wọ́ nínú títojúbọ̀ àti bí ọ̀rọ̀ orí fóònù Obi àti Bishop Oyedepo ṣe lu síta o! – NCC

Ajọ to n risi ibaraẹnisọrọ lorilẹede Naijiria (NCC) ti fesi lori bi awọn ọmọ Naijiria ṣe fi igbe orukọ wọn bọ ẹnu lati igba ti ọrọ ori foonu laarin oludije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party ati oludsilẹ ijọ Living Faith Church, Biṣọọbu David Oyedepo ṣe lu sita.

Laipẹ yii ni iroyin naa jade to si di ranto lori ayelujara pẹlu oniruuru ero awọn eeyan nipa ọrọ awọn mejeji to lu sita ọhun.

Ninu rẹkọọdun ọrọ to lu sita naa ni Peter Obi ti n bẹ Pasitọ Oyedepo wipe ko ba oun ko eniyan jọ lati dibo fun oun ni ẹkun Guusu Ila Oorun ati ni ipinlẹ Kwara.

Bakan naa, ọrọ mii to jẹ jade ni pe Peter ṣe apejuwe eto idibo naa gẹgẹ bi eyi to jẹ ijagun ẹlẹsinjẹsin. Eyi gba gbogbo ori ayelujara kan ti awọn eniyan si n wa otitọ.

Kii ṣe pe awọn mejeji bu ẹnu atẹ lu rẹkọọdu ọrọ naa amọ wọn ti fesi lọna mii eyi to si tun mu ki awuyewuye tohun ti oriṣiriṣi erongba tubọ maa jade lori rẹ.

Awọn ọmọ Naijiria kan ti wa naka alebu si ajọ NCC pe awọn lo wa nidi bi ajọsọ ọrọ naa ṣe lu sita.

Ki ni NCC fi da a pada?

Ajọ NCC sọ ninu atẹjade kan ti adari ẹka ọrọ to kan araalu, Reuben Mouka fi sita pe nipasẹ ilana ajọ NCC abala ti ọdun 2023 atawọn abala ofin orilẹede Naijiria mii to ni ẹ pẹlu rẹ, ajọ yii kii “ko si le tojubọ tabi jẹ ki ọrọ ori foonu ẹnikẹni lu sita”.

“Iroyin ti to ajọ NCC leti lori ayelujara nipa ẹsun titọpinpin tabi ṣiṣe agbejade ọrọ ori foonu eyi ti wọn fi kan NCC latọwọ awọn eeyan tabi ẹgbẹ kan”

“Ajọ yii bu ẹnu atẹ lu ẹsun naa patapata, a si ti ṣe akọsilẹ rẹ tori a ko fi ṣere rara, a ti fi ọrọ naa sun awọn ẹṣọ alaabo to yẹ fun iwadii gidi ati igbesẹ to ba yẹ”.

Atẹjade naa tun tẹsiwaju lati tẹnu mọ ifarajin ajọ NCC si ṣiṣe ojuṣe wọn si awọn ọmọ Naijiria ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin orilẹede Naijiria ati ni ibamu pẹlu bo ṣe yẹ ki ojuṣe wọn ri ni agbaye.

“Bi ko ba wa daa yin loju to, ajọ naa bu ẹnu atẹ lu ẹsun yii a si gba gbogbo araalu nimọran lati kọ eti ikun sii”.