You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Ọdún tó kọ́já ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Akéwì, bí mo ṣe wá ṣe kòńgẹ́ ire tí mo ń lọ Cotonou, Eko àti gbogbo ìlu ...'
Ni awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba, arabinrin kan wa to ti di ilumọka to jale jako tori iṣẹ ewi to yan laayo.
Eyinju Olodumare ni ọpọlọpọ mọ ọ si amọ orukọ rẹ gangan ni Folorunsho Arike.
Iṣẹ Akewi ti wa di ọna kan to n gba pa owo wọle amọ kii ṣe pe ko ni ipenija tirẹ naa.
"Taa ba lọ ibi inawo, ẹẹ maa gbọ ti MC a maa ni, awọn elewi yẹn da ti wọn pe, iṣẹju marun pere lo ni... Wọn o kaa kun".
Eyinju ṣalaye pe iwa yii ti awọn atọkun eto maa n hu ko dara amọ awọn ni ireti ninu awọn eeyan to jẹ wipe boo ba ṣe n ki wọn, ori wọn a maa wu ti awọn mii a si maa bu owo tabua jade.
Eyinju eledumare wa gba awọn eeyan nimọran lati jẹ ki iṣẹ ewi naa gbalẹ kan ko tan kaakiri gẹgẹ bi iṣẹ awọn olrin ṣe maa n tan ki wọn si ma foju kere ewi to jẹ aṣa ilẹ Yoruba.