N kò wá ọkọ o- Motunde Sogunle pariwo síta

Aworan Motunde Sogunle

Oríṣun àwòrán, Instagram/mo,sogunle

Oṣere tiata obinrin, Omotunde Sogunle ti ọpọ mọ gẹgẹ bi Motunde ninu ere ori ayelujara pẹlu Mr Macaroni ni o ti rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ orilẹede Naijria paapa awọn ọkunrin pe oun ko fi igba kankan wa ọkọ .

Motunde sọ eleyi ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu Sunday Scoop nipe ipa ti oun ko ninu ere ori ayelujara ni ọpọ ti gba si otitọ pe bi oun ṣe n gbe igbe aye rẹ niyẹn.

“Isẹ ni mo n ṣe, ti mo si mu ni ọkunkundun sugbọn o ti n di nnkan miiran nitori mo ti n gbiyanju lati jẹ ki awọn eeyan mọ pe n ko wa ọkọ.

“Igbe aye mi yatọ si isẹ ti mo n ṣe, ti n ko si fẹ ki igbagbọ awọn eeyan kan ko si mi ni ọpọlọ.”

Motunde ni ipa ayelujare n ko ni igbesi aye awọn oṣere lo pin si meji sugbọn o gbagbọ pe ti idanilẹkọ ye kuro ba le waye, anfani ayelujara yoo tun le kan si.

“Awọn alebu kan wa ti ayelujara n ṣe fun wa gẹgẹ bi amuludun, se i wọn se ma bu wa tabi sọrọ odi si wa ni ka sọ ni.

“Sugbọn idanilẹkọ ba le wa daada, alaafin yoo wa loei ayelujara ju ti atẹ yin wa lọ,”