You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sáyẹ́ǹsì àbaàdì: Lílo AI láti fi kọ́ àwọn ọmọdé ní ìmọ̀ òfégè
- Author, Jacqui Wakefield
- Role, BBC Global Disinformation Team
Ẹ̀ka tó ń rí sí àwọn ìròyìn òfégè ní ilé iṣẹ́ BBC ti ṣàwárí àwọn ojú òpó kan ní orí Youtube tí wọ́n ń lo ẹ̀rọ AI láti fi ṣe àwọn fídíò láti fi tan ìròyìn irọ́ kiri.
Lára àwọn fídíò tí wọ́n ń fi AI náà ṣe ló jẹ́ ayédèrú nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n sì ń pè é ní òótọ́ fún àwọn ọmọdé láti máa fi kẹ́kọ̀ọ́.
Ikọ̀ ìròyìn BBC ṣe àwàrí àwọn ojú òpó náà tó lé ní àádọ́ta tí wọ́n ń lo èdè tó lé ní ogún láti máa fi pín àwọn ìròyìn òfégè nípa sáyẹ́ǹsì, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti ìmọ̀ ìṣìrọ.
Àwọn fídíò náà ló ń ṣe àfihàn àwọn ìròyìn irọ́ láti jiyàn pé kìí ṣe àwọn ènìyàn ló ń fa àyípadà ojú ọjọ́ àti pé àwọn ẹ̀mí kàn wà nílé ayé tó yàtọ̀ sí ènìyàn àti ẹranko.
Ìwádìí wa fi hàn pé YouTube máa ń ṣàgbékalẹ̀ àwọn ìmọ̀ nípa sáyẹ́ǹsì tí kò tọ̀nà yìí fún àwọn ọmọdé láti ṣàmúlò papọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó dára.
Bí àwọn bá ṣe wò ó sí ni owó ṣe máa wọlé sí
Kyle Hill jẹ́ ẹni tó máa ń lo YouTube láti fi kọ́ àwọn ènìyàn nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, tó sì ní ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó máa ń wo àwọn fídíò tó bá ṣe.
Ó ní láìpẹ́ yìí ni òun máa ń ri tí àwọn fídíò kan máa ń wá sí ojú òpó òun, tí àwọn tó máa ń wo fídíò òun sì ń kàn sí òun nípa àwọn fídíò náà.
Ó ṣàlàyé pé àwọn fídíò náà ni àwọn nǹkan tó jẹ́ pé irọ́ ni wọ́n ló kún orí rẹ̀. Ó ní wọ́n máa jí àwọn ìwádìí tó jẹ́ òótọ́ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì, wọ́n máa wá ṣe àyípadà rẹ̀ láti fi irọ́ ti wọn kún un.
Ó fi kun pé àwọn nǹkan tó jọ mọ́ kàyéfì ni wọ́n máa ń ṣe àwọn fídíò wọn lé lórí, tí wọ́n sì máa wá àkọlé tó dára fún-un pẹ̀lú àwọn àwòrán tó jọjú láti fi fa ojú àwọn ènìyàn sáwọn fídíò náà.
Bí àwọn ènìyàn bá ṣe wo àwọn fídíò náà sí ni owó tó máa wọlé fún wọn náà ṣe ma pọ̀ sí àti pé YouTube náà ní àǹfàní tó máa jẹ níbẹ̀; ìdá márùndínlógójì owó tó bá wọlé fún fídíò lọ jẹ́ ti YouTube.
Àwọn tó ń ṣe àwọn fídíò yìí náà máa ń pè é ní ohun ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èyí tó túmọ̀ sí pé YouTube le ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọmọdé.
“Ara máa ń ta mí tí mo bá ti rí àwọn fídíò yìí nítorí onímọ̀ sáyẹ̀ǹsì tí mo jẹ́, àwọn tó ń ṣe àwọn fídíò yìí kàn ń ṣe wọ́n láti fi pa owó ni láì ṣe wàhálà kankan.”
Ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn tó jẹ́ òfégè
A ṣe àwárí ọ̀pọ̀ ojú òpó YouTube tí wọ́n ń ṣe irú àwọn fídíò báyìí pẹ̀lú lílo àwọn oríṣiríṣi èdè bíi Arabic, Russian, Spanish àti Thai.
Ọ̀pọ̀ àwọn ojú òpó yìí lọ ní àwọn ènìyàn tó ń tẹ̀lé wọn tó lé ní mílíọ̀nù kan, tí àwọn tó sì ń wo àwọn fídíò wọn yìí sì lé ní mílíọ̀nù kan bákan náà.
Kìí pẹ́ síra wọn rárá tí àwọn tó ń fi àwọn fídíò yìí sórí YouTube yìí fi máa ń gbé àwọn fídíò sáwọn ojú òpó yìí, èyí ló jẹ́ kí a rò ó pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé AI ni wọ́n fi ń ṣe àwọn fídíò náà.
AI dàbí àwọn Chat GPT, MidJourney tí wọ́n le ṣe onírúurú nǹkan tí ẹ bá fẹ́ kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ ẹ lè sọ fun pé kọ ya àwòrán ológbò dúdú tó dé adé tó sì máa gbe wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ dípò wíwa àwòrán bẹ́ẹ̀ lórí ayélujára.
Láti fìdí èyí múlẹ̀, a mú fídíò láti àwọn ojú òpó yìí láti ṣàyẹ̀wò wọn láti fi mọ̀ bí wọ́n ṣe jẹ́ tí ìwádìí wa sì fi hàn pé gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n lò tó fi mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò ló jẹ́ èyí tí wọ́n fi AI ṣe.
Ọ̀pọ̀ àwọn fídíò náà ló dàbí èyí tó jẹ́ òótọ́ àmọ́ tó jẹ́ wí pé òfégè ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn.
Ṣíṣe àgbákalẹ̀ àwọn fídíò náà fún àwọn ọmọdé
A fẹ́ mọ́ bóyá YouTube le ṣàgbékalẹ̀ àwọn fídíò tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì rẹ̀ kò tọ̀nà yìí fún àwọn ọmọdé, a ṣí ojú òpó ti àwọn ọmọdé lórí YouTube nítorí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ tí a bá sọ̀rọ̀ ní òhun ni àwọn máa ń lò dípò YouTube Kids.
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin tí a ti ń wo àwọn fídíò ẹ̀kọ́ nípa sáyẹ́ǹsì tó jẹ́ ojúlówó ni àwọn tó jẹ́ òfégè’tí wọ́n fi AI ṣe yìí náà bẹ̀rẹ̀ sí ní wá sí ojú òpó fún wa láti lò.
Bí a bá ṣe ń tẹ ọ̀kan ni ọ̀pọ̀ mìíràn tún ń yọjú.
A ṣe àfihàn àwọn fídíò yìí fún àwọn ọmọdé kan tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́wàá sí méjìlá, àwọn kan ní UK àtàwọn mìíràn ní Thailand láti mọ̀ bóya wọ́n máa gba àwọn nǹkan tí wọ́n rí gbọ́.
Ohun tí fídíò tí a fi hàn wọ́n náà dá lé lórí ni ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀mí kan tó wà nílé ayé tó yàtọ̀ sí ènìyàn àti ẹranko.
Ọmọbìnrin kan ní òun fẹ́ràn fídíò náà àti pé òun kò gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀mí náà wà tẹ́lẹ̀ àma pllú nǹkan tí òun rí náà, òun ti gbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀mí náà wà ní tọ̀ọ́tọ́.
Àmọ́ àwọn kan nínú àwọn ọmọ náà ní mọ̀ pé AI wà lára àwọn nǹkan tí wọ́n lò láti fi ṣe àwọn fídíò náà.
Nígbà tí a ṣàlàyé fún wọn pé AI ni wọ́n fi ṣe àwọn fídíò ọ̀hún àti pé irọ́ ni gbogbo ohun tí wọ́n kó jọ sínú rẹ̀, ẹnú yà wọ́n púpọ̀ tí wọ́n sì sọ wí pé tí kìí bá ṣe wí pé a ṣàlàyé rẹ̀ fún àwọn, àwọn kò bá ti gba àwọn fídíò náà gbọ́.
Ó ṣeéṣe fún àwọn ọmọdé láti gba àwọn nǹkan tí kìí ṣe òọtọ́ gbọ́
Àwọn onímọ̀ ń kọminú lórí àwọn àgbákalẹ̀ tó le da láàkàyè àwọn ọmọdé rú lórí àwọn nǹkan tó jẹ́ òótọ́.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Vicki Nash, adarí Oxford Internet Institute ní YouTube àti Google ṣe ń fi àwọn ìròyìn nípa sáyẹ́ǹsì pawó jẹ́ ohun tí kò bójúmu ní òye tòun.
Claire Seeley tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní UK ní àwọn ọmọdé máa ń kọ́kọ́ gba ohun tí wọ́n bá rí gbọ́ kí wọ́n tó máa béèrè ìbéèrè lórí rẹ̀ bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà si.
BBC kàn sí àwọn iléeṣẹ́ tó ń gbé àwọn fídíò tí wọ́n fi AI yìí ṣe sí YouTube. Ọ̀kan nínú wọn sọ wí pé fún ìdárayá lásán ni àwọn ṣe àwọn fídíò náà fún.
Wọ́n jiyàn pé kìí ṣe àwọn ọmọdé ni àwọn ṣe àwọn fídíò náà fún àti pé kìí ṣe AI ni àwọn fi ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan níbẹ̀.
YouTube sọ fún wa pé YouTube Kids ni àwọn gba àwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn kò bá kọjá ọdún mẹ́tàlá láti máa lò àti pé àwọn ti ṣetán láti yọ fídíò tó bá jọ mọ́ òfégè kúrò ní ojú òpó àwọn.
Àmọ́ wọn kò fèsì lórí àwọn owó tí wọ́n ń pa lórí ìpolówó ọjà ní àwọn ojú òpó ọ̀hún.
Bí AI ṣe ń tẹ̀síwájú, ó ṣeéṣe kó ṣòro láti dá àwọn fídíò tí wọ́n bá fi AI ṣe mọ̀.
Olùkọ́ Seeley ń kọminú tó sì ní àwọn òbí àti olùkọ́ gbọ́dọ̀ múra fún àwọn nǹkan tí ó lè ti ẹ̀yìn èyí yọ.