Ọkùnrin tó jẹ́wọ́ pé òun pa aláwọ̀dúdú 39 jáde láyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọ orileede South Africa nni, Louis van Schoor ti jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrin lẹyin aisan ẹsẹ to daa dubulẹ fun ọpọlọpọ ọjọ.

Schoor lo pa ọpọ awọn eeyan alawọ dudu lasiko ogun ẹlẹyamẹya tp waye lorileede South Africa, eyi ti a mọ si apartheid.

Ọjọbọ, ọsẹ yii ni Louis van Schoor jade laye, ẹni to ba ikọ akọroyin BBC Africa Eye sọrọ laipẹ yii nipa bo ṣe ṣe ikọlu si awọn ẹya alawọ dudu.

Aburo ọkan lara awọn ti Van Schoor pa lasiko to n ba BBC sọrọ, jẹ ko di mimọ pe oun fẹ ki awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ iwadii miran pẹlu bi ọkunrin naa ṣe dero ọrun.

Schoor ṣalaye fun BBC nipa bo ṣe pa awọn eeyan danu lọdun 80s, lasiko ti awọn alawọ dudu n ṣakoso orileede South Africa.

O kere tan, eeyan mọkandinlogoji (39) ni Van Schoor pa lasiko apartheid ni nnkan bii 1980 sisalẹ. Apartheid ni ofin kan to gbe awọn alawọ funfun ọmọ South Africa bori awọn dudu, eeyan dudu si ni gbogbo awọn to pa.

Ọmọ to kere ju ninu awọn to pa nigba naa jẹ ọmọ ọdun mejila. Ila-Oorun London lo ti pa ọmọ naa, iyẹn ni ilu kan to wa lagbegbe Eastern Cape, ni South Africa.

Iṣẹ ọlọdẹ ni Van Schoor n ṣe nigba naa, wọn si ti fun un laṣẹ lati da aabo bo ida aadọrin (70% ) ileeṣẹ awọn eeyan funfun ni South Africa. Awọn bii ile ounjẹ wọn,ile itaja , ileewe ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Fun ọdun pipẹ lo ti maa n sọ pe ọdaran ni awọn eeyan toun n pa naa. Van yoo sọ pe oun mu awọn eeyan naa ṣinkun nibi ti wọn ti n fọ ṣọọbu itaja tabi ieeṣẹ awọn eeyan funfun loun ṣe mu wọn balẹ.

“Ka ṣaa sọ pe apaayan fijilante ni, iwa rẹ ko mọ rara’’ Bẹẹ ni akọroyin South Africa kan, Isa Jacobson, to ti fi ogun ọdun wadii Van sọ nipa apaayan naa.

“Awọn ole kee-kee-ke ti wọn n wa ohun ti wọn maa jẹ nibi ile-ilẹ kaakiri, to ṣee ṣe ki wọn ji ounjẹ diẹ lawọn wọnyi. Alafọwọra pẹẹ-pẹẹ-pẹ ni Van sọ di ọdaran to n pa’’

Lọdun 1991, wọn fọwọ ofin mu Van Schoor, wọn si fẹsun meje to nii ṣe pẹlu ipaniyan kan an, ṣugbọn ti wọn tun pada fi silẹ lẹyin ọdun mejila to ti lo lẹwọn.

O kere tan, awọn mejilelọgbọn ninu awọn to ti pa ni ọlọpaa ṣi n sọ pe Schoor lẹtọ lati pa wọn.

Nigba aye rẹ, Van Schoor sọ pe gbogbo awọn toun pa danu loun mu lọrun ọwọ nibi ti wọn ti huwa ọdaran.