Wo eré ìdárayá mẹ́rin tó lè mú ara rẹ jí pépé

    • Author, Bui Thu
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Nigba mi wa ti ara rẹ ko ni fẹ ṣe ohunkohun, ti yoo kan dabi ẹni wi pe ki o ṣa wa loju kan naa.

Koda, ọkan rẹ gan an le maa ro oriṣiiriṣii nnkan, awọn nnkan yii maa n ṣẹlẹ ti eeyan ba ti ṣe wahala ju.

Amọ, eleyii kii ṣe arun rara, awọn ọna kan ree nilana sayẹnsi to ṣeranwọ fun ọ lori iru nnkan bayii.

Ti o ba fẹ lọ gbe ounjẹ rẹ, ri i gẹgẹ bi anfaani lati ṣe idaraya diẹ.

Iwadii ile ẹkọ Harvard Medical School kan lọdun 2019 sọ pe awọn idaraya diẹdiẹ bayii maa n ṣeranwọ fun ara.

Iwadii tun fidi rẹ mulẹ pe ṣiṣẹ idaraya loorekoore maa n ṣeranwọ fun eeyan ninu agọ ara, kii si jẹ ki ọkan eeyan daru.

Ọjọgbọn Scott Lear ni adari ẹka ile ipoogun Pfizer to n ri si igbogun ti arun rọparọsẹ ati iṣan ara ni Vancouver lorilẹede Canada.

Ọjọgbọn Lear sọ pe ''idaraya diẹdiẹ ni ọpọ iwadii fidi rẹ mulẹ pe o maa n mu ọkan eeyan le.

Awọn to n ba n ṣe idaraya daadaa kii saba ni arun ọpọlọ tabi ki inu wọn poruuru.''

Ọjọgbọn Lear ni ''ara eeyan le ma fẹ ṣe idaraya, ṣugbọn ara maa n gba yigayiaga kete ti eeyan ba ti ṣe e tan.

Iṣẹju mẹwaa ti to lati fi ṣe iru idaraya bayii, koda, o le ma to bẹẹ gan an.''

''Gbe mi kuro nibi nnkan ti mo n ṣe''

James (a fi orukọ yii bo ẹni yii laṣiri ni) sọ pe oun da isẹ duro ni nnkan bi ọdun mẹwaa sẹyin lẹyin ti ọkan oun poruuru nigba toun ṣiṣẹ tan loju ogun nilẹ Afirika.

James to n gbe ni London bayii maa n lọ si gbọngan ere idaraya ni gbogbo igba ki ọkan rẹ lu tuka.

O ni oun ko fẹran ere idaraya yii ṣugbọn o n ṣeranwọ nla fun ara oun.

Ere idaraya yatọ si ogun lilo

Ọjọgbọn Lear gbawọn eeyan ni imọran wi pe ki wọn kọkọ ṣere idaraya ki wọn to loogun kankan.

Rabia Agha, akọṣẹmọṣẹ nipa ere idaraya agọ ara ni Pakistan sọ pe ṣiṣe ere idaraya ni anfaani to pọ fun ọkan eniyan ju oogun lilo lọ.

O ni ere idaraya le mu ọkan eeyan le, o si le wa ojutuu si ọkan ẹni to ba poruuru pẹlu.

Pekky Marquez,ọmọ orilẹede Venezuela to jẹ akọṣẹmọṣẹ nipa eto ilera sọ pe ọtọ laye oogun, ọtọ si laye ere idaraya bakan naa.

O ni ọpọ awọn eeyan tọkan wọn poruuru ni wọn ṣe ere idaraya ti o si ṣiṣẹ fun wọn.

Marquaz tun ni awọn kan naa ti wọn loogun ri iṣẹ ti oogun ṣe fun wọn.

Ere idaraya marun to le ṣe anfaani fun ọkan eeyan

1. Kẹkẹ gigun

Irin ririn, ere sisa, kẹkẹ gigun ati odo wiwẹ maa ṣe anfaani fawọn ti ọkan wọn ba poruuru.

Iwadii fihan pe kẹkẹ gigun tabi ere sisa fun ogun iṣẹju si ọgbọn iṣẹju le jẹ ki ara eeyan balẹ fun igba pipẹ.

Ere idaraya maa n fun ara lokun, o si maa n jẹ ki ọkan eeyan yigbi.

2. Ere idaraya fun okun

Awọn ere idaraya bii irin gbigbe, ati irin rinrin maa n mu adinku ba iporuuru ọkan.

O tun n maa n jẹ ki ọkan eeyan balẹ.

Gbigbe irin lojoojumọ maa n jẹ ki eeyan jẹ awọn anfaani yii daadaa.

3. Ere idaraya Yoga

Ere idaraya yoga ati tai chi maa n ṣe anfaani fun agọ ara.

Ṣiṣe eyi fun bii wakati kan si wakati kan aabọ fun igba meji si mẹta lọsẹ maa n jẹ ki ara eeyan balẹ.

4. Ere idaraya to gbinaya (HIIT)

Ti eeyan ba fẹ ṣe ere idaraya fun igba perete to yoo si ri anfaani nibẹ, o ni lati karamọ ọ daadaa.

Ṣiṣe ere idaraya fun bii wakati kan ati iṣẹju mẹẹdogun daadaa le jẹ nnkan kan naa pẹlu ẹni to n ṣe ere idaraya diẹdiẹ.

5. Ere idaraya ojoojumọ

Awọn idaraya bii gigun akasọ, irin rinrin ati iṣẹ ile ṣiṣẹ naa maa n ṣeranwọ fun agọ ara.

Ti eeyan ba le maa ṣe eleyii fun iṣẹju mẹẹdogun lojoojumọ, o le mu adinku ba ki ọkan eeyan poruuru.

Sayẹnsi lori ere idaraya

Eeyan si le ṣe akara, tabi ki eeyan ma ṣiṣẹ ninu oko kekere to maa n wa ninu ọgba ile.

Wendy Suzuki, dokita onimọ nipa ọpọlọ sọ pe ere idaraya maa n ṣe anfaani fun ọpọlọ.

Ipa akọkọ

Ere idaraya maa n nipa kiakia lori ọpọlọ

Ipa keji

Ipa keji ti ere idaraya maa n ni lori ópọlọ ni pe o maa n jẹ ki eeyan le maa tẹti si ọrọ daadaa.

Ipa kẹta

Ṣiṣe ere idaraya ni gbogbo igba maa n pese awọn kẹmika to maa n ṣanfaani fawọn sẹẹli inu ara.

Bakan naa lo maa n jẹ ki ọpọlọ ni okun sii.

Idi niyii to fi jẹ pe ere idaraya to ba le mu eeyan laagun maa n fun ara ni okun, o si tun maa n mọkan eeyan le.