Trump ni US yóò máa ṣàkóso Venezuela, ṣe àtúnṣe sí ẹ̀ka epo rọ̀bì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump ti kede pe US yoo maa ṣe akoso ìṣejọba Venezuela títí wọn yoo fi ri daju pe ijọba bọ sọwọ ẹni to yẹ.

Aipẹ yii ni US kọlu Venezuela, ti ọwọ sí tẹ olori orilẹede naa, Nicolas Maduro.

Bakan naa ni ijọba US ni awọn ileeṣẹ epo rọbi US yoo se atunṣe si ohun alumọni to bajẹ, ti wọn yoo si bẹrẹ si ni pawo si apo ijọba.

Ọjọ Satide, ọjọ kẹta oṣu kinni ni US kọlu Venezuela pẹlu awọn ọmọ ogun, tí ọwo si tẹ Maduro ati iyawo rẹ, Cilia Flores, ti wọn si ti gbe wọn kuro ni orilẹede naa.

Venezuela tí kede ilu o fararọ pajawiri, ti igbakeji Aarẹ si ti kede Maduro ní kan ni olori wọn.

Baalu nla ni wọn fi gbe Maduro ati Flores kuro ni olu ilu Venezuela ni owurọ ọjọ Satide.

Awọn mejeeji ni wọn fi ẹsun kan pe wọn lọwọ ninu kiko ogun oloro ati ohun ado oloro wọ ilu naa.

"Wọn foju wina ofin ilẹ Amẹrika ni ile ẹjọ Amẹrika ni ori ilẹ Amẹrika," Ijọba US kede.

Ààrẹ America, Donald Trump kógun kọlu Venezuela, Ó ní ọwọ́ ti tẹ ààrẹ orílẹ̀èdè náà àti ìyàwó rẹ̀

Aarẹ Donald Trump ni ọwọ awọn ọmọogun orilẹede Amẹrika ti tẹ ààrẹ orilẹede Venezuela, Nicolás Maduro ati iyawo rẹ lasiko ikọlu nla kan ti ileeṣẹ ologun Amẹrika gbe kọlu ilu Caracas tii ṣe olu ilu orilẹede Amẹrika.

Aarẹ Trump ko ṣalaye pupọ lori bi wọn ṣe mu Aarẹ Maduro, bakannaa lawọn alaṣẹ ijọba orilẹede Venezuela pẹlu ko tii fi idi eyi mulẹ.

Aarẹ Donald Trump tun ti paṣẹ ki ileeṣẹ ogun lorilẹede Amẹrika o kọlu awọn agbegbe kan lorilẹede Venezuela.

Iroyin sọ pe ibugbamu loriṣiriṣi n waye bayii kaakiri awọn agbegbe kan, titi kan awọn ibudo ologun ni ilu Caracas.

Aworan ati fidio eefin ati ina to n ru soke lalala ni ilu Caracas tii ṣe olu ilu orilẹede Venezuela gba gbogbo ilu kan.

Awọn ti o wa lagbegbe to sun mọ ibudo ologun La Carlota to wa ni aringbungbun ilu naa, ati ibudo ologun Fuerte Tiuna sọ pe awọn ibudo ologun mejeeji yii fara ko ina ikọlu naa.

Ki nidi ti Amẹrika fi n kọlu Venezuela?

Awọn iroyin kan tilẹ tun sọ pe ọpọlọpọ awọn ilu to yi ilu Caracas ka ni ko ni ina bayii, bẹẹni awọn iroyin ti a ko le fidi rẹ mulẹ pẹlu n sọ pe awọn baluu n fo kaakiri ofurufu ilu naa bayii.

Igbesẹ yii n waye lasiko ti aawọ laarin Amẹrika ati Venezuela n ba ara wọn wọ ṣokoto kan naa, ti Amẹrika si n kọlu awọn ọkọ ojuomi ti wọn n ko ogun oloro ni agbami Caribbean.

Orilẹede Amẹrika n sọ pe makaruru ni ibo to gbe aarẹ orilẹede Venezuela, Nicolas Maduro de ipo, ati wi pe o ṣe agbodegba fun okoowo ogun oloro kaakiri orilẹede naa.

Orilẹede Venezuela n sọ pe, awọn igbesẹ ti Amẹrika n gbe lẹnu ọjọ mẹta yii, titi kan gbigbẹsẹ le awọn ọkọ akepo loju omi lati orilẹede naa, kun ara igbesẹ ti wọn n gbe lati fi ipa yọ Aarẹ Maduro nipo, ki wọn si le maa ṣe akoso ọgbun epo rọbi orilẹede Venezuela.

Ki ni igbesẹ ti Ijọba Venezuela gbe pẹlu ikọlu yii?

Ijọba orilẹede Venezuela ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ Amẹrika lati ṣe ikọlu si orilẹede rẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin ti ikọlu naa bẹrẹ, ijọba orilẹede Venezuela ṣalaye pe ọna ati "fipa gba awọn ohun alumọni Venezuela, paapaajulọ epo atawọn ohun alumọni inu ilẹ" ati lati " fi agidi bu omi pa ina eto oṣelu" orilẹede naa ni.

Aarẹ Orilẹede Venezuela, Nicolás Maduro ti buwọlu iwe aṣẹ igbesẹ tako ikọlu ilẹ okeere, o si ti rọ gbogbo awọn ologun ati oṣiṣẹ ilu lati bẹrẹ igbesẹ pajawiri bayii